Music Video
Music Video
Credits
PERFORMING ARTISTS
Sola Allyson
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Sola Allyson
Composer
PRODUCTION & ENGINEERING
TOBI ALUKO LATECHS
Producer
Lyrics
Àgbọ́nmáàgbẹ́ ni oore lát'ọ̀dọ̀ Olúwa o
Respond same.
Ẹni Ń p'àṣẹ oore tí ò lè tán l'Olúwa o
Respond same
Níbo l'oore tí ń wá bí ò ṣ'ọ̀dọ Bàbá wa -
Rrspond same
Àgbọ́nmáàgbẹ́ l' òkun
Àgbọ́nmáàgbẹ́ l'ọ̀sà
Torí Àgbọ́nmáàgbẹ́ ni Baba t'Ó ó p'àṣẹ wọn
Baba Olóore
Baba Ọlọ́orẹ /2x
Oore tí ò ṣeé ṣ'àlàyé, oore tí kìí tán
Ọ̀dọ̀ Rẹ ni wọn ti ń wá Bàbá Àgbọ́nọ̀gbẹ, Kòs'ẹ́ni t'ó dàbí ì Rẹ, bùsọ̀bùsọ̀ l'oore e Rẹ, Tal'ó lè bi Ọ l'ẹ́jọ́ àbùùbùtán ni
Ọlọ́lá t'á ò le ka, Olóore tí ò ṣeé d'áyelé, mo p'áyà Rẹ Olóore mi
Oore tí ò ṣeé d'íye lé, Ìwọ l'Ó nií l'ọ́wọ́
Mo p'áyà Rẹ Olóore àgbọ́nọ̀gbẹ
Ọba t'Ó Ń fúnni l'áyé lò
Olùfúnni t'á ò lè dí l'ọ́wọ́
K'á r'íbùkún lò tí ò lè tán l'áye ńbí Ìwọ nìkan ní ń fúnni
Ẹnit'Ó ṣàánú ù mi, Ẹnit'Ó fún mi ní ìrànwọ́ lò
Fi mí hàn bíi Tìrẹ Olóore agbọ́nọ̀gbẹ
Mo rí òṣùpá lókè, òrùn náà òkè l'ó ti ńràn
Ìràwọ̀ wà ńbẹ̀ ó ńṣe tiẹ̀ òṣùmàrè náà ńfàwọ̀ ṣ'ẹwà
Lát'ayébáyé wọn ò mà tán wọn ò sì lè tán láéláé
Ore tí ò lè tán ẹwà tí ò lè ṣá ògo tí ò lè tí láéláé
Ìwọ nìkan l'Ó ni ògo, Ìwọ nìkan l'Ó ni ọla
Mo júbà Rẹ Olóore mi
Irú ore yí ni mo f'ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn bèrè Bàbá gbée bùn mi o
Màá ṣáà máa wà l'étò Rẹ Olóore àgbọ́nọ̀gbẹ
Written by: Sola Allyson