Teledysk
Teledysk
Kredyty
PERFORMING ARTISTS
Sola Allyson
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Sola Allyson
Composer
Wole Adesanya
Composer
PRODUCTION & ENGINEERING
Wole Adesanya
Producer
Tekst Utworu
[Verse 1]
Dúró tì mí o olólùfẹ́
Ìfẹ́ tí kò l'ábùkù ni k'o bá mi lò
Dúró tì mí o olólùfẹ́
Ìfẹ́ tí kò l'àbàwọ́n ni k'óo bá mi lò
[Chorus]
Ìfẹ́ bí eji òwúrọ̀
Lát'àgbàlá Elédùmarè l'ó ti ṣẹ̀ wá
Ìfẹ́ t'ó t'òrò minimini
T'ábàwọ́n ayé è kan ò le è bàjẹ́ o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
[Verse 2]
Fẹ́ mi bí ojú ti ń fẹ́'mú
Fẹ́ mi bí irun ti ń f'órí
Fẹ́ mi bí eyín ti ń f'ẹ́nu
Fẹ́ mi tẹ̀mítẹ̀mí
Fẹ́ mi tọkàntọkàn
Fẹ́ mi taratara
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
Fẹ́ mi bí ojú ti ń fẹ́'mú
Fẹ́ mi bí irun ti ń f'órí
Fẹ́ mi bí eyín ti ń f'ẹ́nu
Fẹ́ mi tẹ̀mítẹ̀mí
Fẹ́ mi tọkàntọkàn
Fẹ́ mi taratara
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
[Chorus]
Ìfẹ́, Ìfẹ́ bí eji òwúrọ̀
Lát'àgbàlá Elédùmarè l'ó ti ṣẹ̀ wá
Ìfẹ́ t'ó t'òrò minimini
T'ábàwọ́n ayé è kan ò le è bàjẹ́ o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
[Verse 3]
Bá mi ṣ'òtítọ́ mo fẹ́ ọ tòótọ́
Bá mi ṣ'òdodo mo fẹ́ ọ pẹ̀lú òdodo
Bá mi ṣ'òtítọ́ olólùfẹ́ mo fẹ́ ọ tòótọ́
Bá mi ṣ'òdodo mo fẹ́ ọ pẹ̀lú òdodo
B'ógiri ò bá la'nu aláǹgbá ò lè w'ògiri
B'ógiri ò bá la'nu aláǹgbá ò lè w'ògiri
Ẹlẹ́ẹ̀dá l'ó yàn wá papọ̀ èṣù kò ní yà wá o
[Chorus]
Ìfẹ́ bí eji òwúrọ̀
Lát'àgbàlá Elédùmarè l'ó ti ṣẹ̀ wá
Ìfẹ́ t'ó t'òrò minimini
T'ábàwọ́n ayé è kan ò le è bàjẹ́ o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
[Verse 4]
A máa l'ówó l'ọ́wọ́
A máa bí'mọ lẹ́'mọ
A máa ṣ' ayọ̀ m'áyọ̀
A máa ṣ'ọlá m'ọ́lá
K'á ṣáà mú'fẹ́ Elédùmarè ṣẹ̀ l'áìṣẹ̀tàn o
A máa l'ówó l'ọ́wọ́, a máa l'ówó l'ọ́wọ́
A máa bí'mọ lẹ́'mọ
A máa ṣ' ayọ̀ m'áyọ̀
A máa ṣ'ọlá m'ọ́lá
K'á ṣáà mú'fẹ́ Elédùmarè ṣẹ̀ l'áìṣẹ̀tàn o
[Chorus]
Ìfẹ́, Ìfẹ́ bí eji òwúrọ̀
Lát'àgbàlá Elédùmarè l'ó ti ṣẹ̀ wá
Ìfẹ́ t'ó t'òrò minimini
T'ábàwọ́n ayé è kan ò le è bàjẹ́ o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
[Verse 5]
Gb'ámọ̀ràn mi olólùfẹ́ ẹ̀ mi
Olùrànlọ́wọ́ l'a fi mí ṣe fún ọ lát'ọ̀run wá
F'etí s'ámọ̀ràn mi olólùfẹ́ mi
Olùrànlọ́wọ́ l'a fi mí ṣe fún ọ lát'ọ̀run wá
K'á jọ rìn k'á ṣ'ògo f'órúkọ Ọlọ́run
Alábarìn l'a fí mí ṣe fún ọ lát'ọ̀run wá
M'ọ́kàn kúrò nínú asán ayé ẹtàn ò da ǹkankan fún ni
Ìfẹ́ àt'ọpẹ́ l'ó lè mú wa l'áyé já láìlábàwọ́n o
M'ọ́kàn rẹ kúrò nínú asán ayé ẹtàn ò da ǹkankan fún ni
Ìfẹ́ àt'ọpẹ́ l'ó lè mú wa l'áyé já láìlábàwọ́n o
[Chorus]
Ìfẹ́, Ìfẹ́ bí eji òwúrọ̀
Lát'àgbàlá Elédùmarè l'ó ti ṣẹ̀ wá
Ìfẹ́ t'ó t'òrò minimini
T'ábàwọ́n ayé è kan ò le è bàjẹ́ o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
Ìfẹ́ o, Ìfẹ́ bí eji òwúrọ̀
Lát'àgbàlá Elédùmarè l'ó ti ṣẹ̀ wá
Ìfẹ́ t'ó t'òrò minimini
T'ábàwọ́n ayé è kan ò le è bàjẹ́ o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
[Outro]
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn o (Ọ̀rẹ́ ọkàn mi)
Ayanfẹ ọkàn mi ìpìn jọ̀'pín ìrìn jọ̀'rìn l'a ṣe ń r' ìrìn yí o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn o
Olólùfẹ́ fẹ́ràn mi l'áìṣẹ̀tàn
Written by: Sola Allyson, Wole Adesanya