album cover
APPRECIATION
39
Music
APPRECIATION was released on January 19, 2025 by Fuji Repete/K1 De Ultimate Media as a part of the album TRIBUTE TO MY MOTHER
album cover
Release DateJanuary 19, 2025
LabelFuji Repete/K1 De Ultimate Media
Melodicness
Acousticness
Valence
Danceability
Energy
BPM

Music Video

Music Video

Credits

PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
K1 De Ultimate
Performer
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Drums, Keyboards
COMPOSITION & LYRICS
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Songwriter

Lyrics

Ẹ má bìínú pípẹ́ tí mo pẹ́ lẹ́yìn
Mo lọ ṣe t’ọmọ lórí òbí ẹni ìyá mi Alimo Sadia
Sadia relé, thank you
Alimo Sadia ó relé
Kò kọ́kọ́ yé mi àfi ìgbà tí àwọn ayé ń kími pé mo kú oríire arábámbí
Irú oríire kínni?
Kí ìyá ẹni ó kú
Ọmọ tí ò ní rí màmá ẹ̀ mọ́ o
Wọ́n wá ń sọ fún mi wí pé o ti ṣẹ́gun oṣó
O ṣẹ́gun àjẹ́ torí kínni?
Ọmọ tó bá gbẹ̀yìn òbí ẹ̀ òun l’Ọlọ́hun Ọba ń fẹ́
Àìmọye èèyàn ni wọ́n ń retí irú èyí
Ìyá tó bí wọn ó ti lọ ò ní kékeré
Àwọn òbí wọn f’ayé lẹ̀ ìgbà tí wọ́n ń bẹ lọ́mọdé
Èmi dúpẹ́ Ọlọ́hun Alimotu Sadia ọmọ Akérédolú
Ọmọ Ọba nìlúpéjú Èkìtì aya Ọba níjẹ̀bú òde
Ìyá mi Alimo Sadiatu o
Ó kọjá Ọgọ́rùn-ún kó tó relé lọ sùn ọmọ Anífowóse Ọlọ́hun bàbá mo dúpẹ́
(Arabic Recitation)
Ṣùgbọ́n irú ọjọ́ èní bí ǹ bá wábí Wasiu arábámbí
Ará a mi ò ní balẹ̀ ọmọ Anífowóṣe o ọmọ òkú ọ̀run
Mufuti, Mufti ó tóbi lọ́wọ́ mi Wasiu Àyìndé
Yàtọ̀ sí pé nínú ẹ̀sìn very very important
Ń ṣe ni Suleiman
Iṣan ọrùn Adégoróyè tipẹ́tipẹ́
A sì ti jọ ń ṣeré bọ̀ lọ́mọdé
Sheu Farouq àdúrà ẹ ti gbà lórí wa
Àmọ̀pé Sadia ti lọ Automatic o ti gbẹ́wù yẹn wọ̀
Kò ní wọ̀ ẹ́ lọ́rùn Àmín
Wàá ṣe ìyá fún mi pẹ́ Ramotallahi mi Àmọ̀pé adé o
Àmọ̀pé adé wàá ṣe ìyá fún mi pẹ́ pẹ́ pẹ́ lowú ń ṣ’arọ́
Mo kí ẹ kí ẹ Àmọ̀pé o
O kú oríire Àmọ̀pé adé Alhaja Ramota
KC
KC
Ẹ gbówó náà jáde (Adé orí ọ̀kín)
Ìyá mi kú, owó la máa ná
A máa kó dollar jáde (owó la máa ná)
Olorì Mariam aya onílé òrìṣà máa wolẹ̀ máa ràba aya t’Ọ̀nirìṣà
Owó la máa ná
Seida, kẹ ya kó dollar jáde (Owó la máa ná)
Dàmọ́lá, Anifata Monsuratu owó la máa ná
Miwa sọ fún ọkọ ẹ ẹ lọ kó dollar jáde (owó la máa ná)
Bosede ẹ kó dollar jáde (owó la máa ná)
Orí ò ṣe wá lọmọ olókùú ò sí nílé
Wasiu Àyìndé mo dúpẹ́ fún Ọlọ́run (Adé orí ọ̀kín)
Wọ́n ń bi ẹ́ Muhammadu Kazeem ọmọ Owólabí
Wọ́n ní ṣe o léèyàn, o ló o lẹ́ni lẹ́yìn ẹ o
Wọ́n ní tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ìrìn-àjò bíi wákàtí méjì
Gbé phone àwọn èèyàn láàrin Ìṣẹ́jú kan sí ìkẹta
Ko sì fún wọn lásìkò kí wọ́n gbórí wọlé
Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì mi
Díẹ̀ ṣá ni mo pè Ọmọtógbọ́láhàn igba ló jẹ́ mi
Ẹ̀yin èèyàn ló ń bẹ lẹ́yìn òrò arábámbí
Àlàmú adé ọkọ Ọmọ́táyọ̀ mi Àlàmú o ṣeun o
Àdúrà ẹ á máa gbà lójoojúmọ́
Àlàmú tẹ rí yẹn èèyàn ni
Kazeem Owólabí mi èèyàn ni
Moshood Ajide tẹ rí yẹn èèyàn ni
Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́ dúpẹ́
Mo tú pẹ̀pẹ́ ọpẹ́ dá
Muhammadu Kazeeme
Sheikh Isiak ọmọ Agbariigidana ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Mo dúpẹ́ dúpẹ́
Imam NANWAT Àyìndé mi Wasiu mo dúpẹ́ dúpẹ́
Imam Ẹ̀pẹ́, Àkànní Akumari ọmọ Adéṣọpẹ́
Ètí inú
Gbogbo èèyàn everybody wọ́n wá ń wọlé
Àkànbí olódó idẹ
Presidenti mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ọmọ Habibatu
Àkànbí ọmọ ìyálọ́jà bàbá ìyálọ́jà
Ó ní Habiba ìyálọ́jà àgbà àti Alimotu Sadia ó ní wọ́n ti jọ ríra wọn báyìí
Wọ́n dẹ̀ ń ṣe ìpàdé, ó ní kí gbogbo àdúrà máa lọ beeee
Àkànbí mo dúpẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ bàmi
Ó dẹ̀ ṣe ní àdúrà fún mi ó ní ojú mi ò ní ríbi
Ó ní ìyá kan ò ní jẹ ẹ́ ọmọ òkú ọ̀run
A ò dẹ̀ kí ń lẹ́ni lẹ́yìn kíyá ó tún jẹni President mo dúpẹ́ dúpẹ́
His Excellency Babájídé ọmọ Sanwóolú
Deputy Governor Hamzat Ọbáfẹ́mi
Governor Dàpọ̀ Abíọ́dún
Governor Ṣèyí Mákindé mo ki yín ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kálukù ni wọ́n gbórí wọlé
Àdìsá bí èèyàn bá lẹ́yìn arábámbí
Ẹsékẹsẹ̀ ni Bíọ́lá ló volunteer ó lẹ́yin ẹ máa lọ sìnkú
Òun ma lọ sékòó òun á lọ stand in ọmọ á jẹ́ ẹ
Wàá pe èèyàn márùn-ún igba ló máa jẹ́ ẹ Àmín o
O kú àdúrótì wọ́n pínṣẹ́ fúnra wọn ni
Bọ́ládé ìyẹn re Central mosque ó lọ di mọsalasi mú
Ó di baba mesinku òun pẹ̀lú ofulu gbogbo wọn ni wọ́n ìdílé mú
Abíọlá àní èèyàn mẹ́wàá lo máa pè igba ló máa jẹ́ gbogbo wọn
Alao Sulemona ó gbórí wọlé
Bí a ṣe dé mọ́ṣáláṣí
Ajibola Pasuma ó gbórí wọ̀lé
Gbogbo wọn ń pè mí lọ́tùn-ún lósì ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Ìyẹn lẹni àkọ́kọ́ pè Àdùnní Risikiyatu Afọláshadé
Ọlámilékan olóòtú ọlọ́lá Madasa gbogbo Akilẹ̀ Ìjẹ̀bú
Bó ṣe ṣẹlẹ̀ gbàrà egúngúngbohùn ó ń gbọ́
Ó dẹ̀ dé ìlú Ìjẹ̀bú Òde
Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Adégbóyèga Alátiṣe
Mutiu ọmọ Ààrẹ òun ló wá ṣe aṣojú aṣojú President arábámbí
On behalf of Ọ̀yọ́ State Owóṣeéní Fatai ó gbórí wọlé
Fìjàbí onílẹ̀ obì Akin ó move gbogbo èrò láti Ìbàdàn l’Ólúyọ̀lé ilé kún
Abdulwasiu ọmọ Jẹ́nrádé ìlú bàbá Isah Ẹlẹlẹ l’Ólúyọ̀lé ilé
Gbogbo yín mo dúpẹ́ dúpẹ́ fún èró pọ̀
A ò lè pe gbogbo èèyàn tán
Bí a ṣe ń kúrò nítẹ́ Àyìndé Musiliu Ayédáadé
Òun náà gbórí wọlé sílùú Ìjẹ̀bú Òde
Kábíèsí Awùjalẹ̀ Ọba Adéwájú
Ọlọ́jà nílùú Ẹ̀pẹ́ ilé àti Aláyélúwà tuntun Kábíèsí ìmọ̀pẹ̀
Ọba mẹ́ta ní ọ̀pẹ̀ mi
Kábíèsí láti makun omi, Kábíèsí Àkárìgbò
Kábíèsí Alárá èrò pọ̀ lọ rẹpẹtẹ
Bí a ṣe ń kọ Inalilahi
Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà a jọ ń ke ni
K1 De Ultimate ta fi gbé ṣẹ
Kábíèsí Makun omi gbogbo ẹ̀yin Ọba ládé ládé
Orímolúsì Ìjẹ̀bú Igbó
Èbúmàwá àgọ́ Kábíèsí Ọ̀gọ̀gọ̀
Àti Òrúgbò Kábíèsí Òrúgbò ẹ kú àdúrótì mo dúpẹ́ dúpẹ́
Baba wa Àkànní mi Rasaki Eleganza Ọkọya
Àti Afọlashadé Ìṣẹ́jú Ìṣẹ́jú Àyìndé mi ni wọ́n ń pè
Wọ́n sì ń ṣ’àdúrà fún mi K1 De Ultimate
Wọ́n ní o kú oríire Àyìndé o
Written by: Olasunkanmi Ayinde Marshal
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...