Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band 的热门歌曲
制作
出演艺人
Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
表演者
作曲和作词
Olusegun Akinsete Akinlolu
词曲作者
歌词
Gbogbo ero ti ngo ro l'oni, rere ni o (rere ni o, rere)
Gbogbo ọrọ ti ngo fọ loni, ye, rere ni o (rere ni, rere ni)
Rere loko, lodo, loke, nilẹ, lọjọ gbogbo
Oun gbogbo ti nwo ṣe loni rere ni o (rere ni o, rere)
Gbogbo irin ti ngo rin loni, ye, rere ni o (rere ni, rere ni)
Rere ni'bere ni'dubulẹ, ni'dide ni'joko, lọjọ gbogbo
Rere loko, lodo, loke nilẹ, lọjọ gbogbo
Oun gbogbo ti mo wo loni rere ni o (rere ni o, rere)
Ibi gbogbo ti mo tẹ loni, ye, rere ni o (rere ni, rere ni)
Rere niyẹwu, nigbagede, l'òwúrọ, lalẹ, lọjọ gbogbo
Oun gbogbo ti mo ba dimu rere ni o (rere ni o, rere)
Gbogbo ibi ti mo gb'ẹsẹ le, ye, rere ni o (rere ni, rere ni)
Rere lotun losi, loko, lodo, lọjọ gbogbo
Rere ni'bere, ni'dubulẹ, ni'dide, ni'joko, lọjọ gbogbo
A ṣẹṣẹ bere ayọ ni o (ṣẹṣẹnṣẹṣẹ)
A ṣẹṣẹ bere adun ni o (ṣẹṣẹnṣẹṣẹ)
Ire otun lo wọlé o (ṣẹṣẹnṣẹṣẹ)
Alafia gbe pẹlu awa (ṣẹṣẹnṣẹṣẹ)
Ibalẹọkàn l'ogun awa o (ṣẹṣẹnṣẹṣẹ)
Aikubaalẹ ọrọ (ṣẹṣẹnṣẹṣẹ)
A ṣẹṣẹ bere igbadun ni o
Written by: Olusegun Akinsete Akinlolu