क्रेडिट्स

PERFORMING ARTISTS
Tope Alabi
Tope Alabi
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Patricia Temitope Alabi
Patricia Temitope Alabi
Songwriter

गाने

[Verse 1]
Mo ri ire ayo ibukun
Mo ri ogo ayanmọ to pe pere
Ola po jaburata, ọrọ agbon-i-gbe
Gbogbo eyi ti mo ri emi lo ni won
Baba lo fi fun mi
[Chorus]
Ore ọfẹ Jesu
Ore ọfẹ Jesu
Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi leyin
Ore ọfẹ Jesu o
Ore ọfẹ Jesu o
Ore ọfẹ Jesu ati anu lo to mi leyin
[Verse 2]
Ọnà mi la igi aye dina ti wo womu womu
Dipo akete aisan sekere ọpẹ lo gbe le mi lọwọ
Bo ti wí tele ayo mi ku ko i tan Oluwa lo tun mi se
Isoji ọpẹ laye mi gba b'Oluwa ti fe fún mi (B'oluwa se fẹ fun mi niyen)
[Chorus]
Ore ọfẹ Jesu
Ayo mi ku o po nle repete (Ore ọfẹ Jesu)
Ko le tan bẹẹ ni (Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi leyin) Oluwa lo tun mi se o
Isoji ọpẹ laye mi gba
(Ore ọfẹ Jesu) N o maa gbe kiri ni
(Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi lẹyin) Gbogbo agbaye ni wo n ti ṣe isoji ọpẹ
[Verse 3]
Alayo ni mi o, ore ọfẹ ati anu
Lo n to wa oh at'ẹmi atilemi leyin oh
Bi mo ba jade, bi mo ba wole (Ire Ire)
Bi mo ba sun lale ti mo ji lowuro (Ire ire)
Adawole mi ko yori si ogo (Ire ire)
Ore ọfẹ Jesu kristi ati anu lo deyin leyin mi (Ire ire)
Oro mi ma sope ni gbogbo ona ni o (Ire ire)
Ibi ti mo ba tẹ a sun rere fun mi (Ire ire)
Ire níwájú mi, ire leyin ire lo n ro fun mi o (Ire ire)
Ayo legbe otun, legbe osi, níwájú leyin mi o (Ire)
Ìfẹ oluwa Jesu kristi ko le fi mi silẹ lai lai (Ire)
[Chorus]
Ore ọfẹ Jesu
Ore ọfẹ Jesu (O to mi leyin, o bami gbe, o bami sun, o bami lo) Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi leyin
Gbogbo ibi ti mo ba tẹ (Ore ọfẹ Jesu)
Mo gba bẹ nile (Ore ọfẹ Jesu)
Anu wa mi ri, ore ọfẹ sare tẹ mi leyin(Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi leyin)
[Verse 4]
Olorun lo se mi bẹ
Ni tooto ki ire ati anu ore ọfẹ
Ko ma to ọ lẹyin ni gbogbo ọjọ ayé rẹ
Adura ojo pipe ko gba esi ayo logan, amin o
Alanu ko wa e ri, ko ma se laala lasan
O ni se mú fún ota, bẹẹni o ni teni tika laye to wa o
Awotele rẹ àti tode yo ma bi ogo fun ọ ni
Ore ọfẹ ati ìfẹ ọlọrun ko ma ko ti wa pa, ko ma ko tiwa pa
[Chorus]
Ore ọfẹ Jesu
Ore ọfẹ Jesu (E tewo adura mo wí o)
(Ore ọfẹ ati anu, ojurere ati ìfẹ oluwa ko ma tẹle wa) Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi leyin
Ore ọfẹ Jesu
Ore ọfẹ Jesu
Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi leyin
(Awa lo sale) Ore ọfẹ Jesu
(Awa lo da fún) Ore ọfẹ Jesu
(Ohun lo de mi fún, inu rẹ ni mo ti je mo ti mú) Ore ọfẹ Jesu ati anu lo n to mi leyin (Bàbá lo se be)
Written by: Patricia Temitope Alabi
instagramSharePathic_arrow_out

Loading...