Lirik

Eni ba mo 'nu ro, lo le mo ope da Eni ba ni arojinle a saa ma dupe Emi mo 'nu ro, mo ya a wa dupe Olorun ti a ko le da duro, mo gbe O ga o Olorun ti a ko le mu lowo dani Mo gbe O ga o Too ba loya ta lole da O duro, eto inu Re lo wa, eto owo Re lowa Mo gbe O ga o Olorun ti a ko le da duro, mo gbe O ga o Kabiyesi, Kabiyesi Re, Baba Agba Kabiyesi, Kabiyesi Re, Oba awon oba Kabiyesi, Kabiyesi Re, Baba Agba Kabiyesi, Kabiyesi Re, Oba awon oba Kabiyesi Re o, Baba Agba Oba to joko lori ite o, maa sola Re lo Oluwa Kabiyesi, Kabiyesi Re, Baba Agba Kabiyesi, Kabiyesi Re, Oba awon oba O fi imole s'aso bora Oba to f'imole s'aso bora Ori obiri aye lo joko si, imole lo fi s'aso bora Oba to f'imole s'aso bora O fi imole s'aso bora Kabiyesi Re Oluwa Emi mi n bu ola fun O nigba gbogbo Oba mi Ni gbogbo aye ko seni to da bi Re, Oluwa Iwo to n joko sinu awon orun, Oluwa O fi imole s'aso bora Oluwa mo gbe O ga o Awon orun n ba mi yin O o, pe O se Oluwa mo gbe O ga o Awon orun n ba mi yin O o, pe O se Oluwa mo gbe O ga o Gbogbo ise Re n ba mi yin O o, pe O se Mo da ohun mi po mo gbogbo ise Re, mo so bee, O seun Oluwa mo gbe O ga o Awon orun n ba mi yin O o, pe O se A yin O, Oba mimo A yin O, Oloore wa A yin O, Olugbala Iwo lo n s'agbara wa A yin O, Oba mimo A yin O, Oloore wa A yin O, Olugbala Iwo lo n s'agbara wa A yin O o, Oba mimo Ebo ope wa ree o Lat'ogbun okan wa wa ni Wa gba a Oluwa Olorun A yin O, Oba mimo A yin O, Oloore wa A yin O, Olugbala Iwo lo n s'agbara wa Iwo ni mo wa gbe ga Iwo ni mo wa f'iyin fun Olorun mi to n gbe nibi giga Iwo ni mo wa gbe ga Iwo ni mo wa gbe ga Iwo ni mo wa f'iyin fun Olorun mi to n gbe nibi giga Iwo ni mo wa gbe ga Iwo ni mo wa gbe ga o Oba to r'ojo aanu s'ori iseda mi, Oluwa Olorun mi to n gbe nibi giga Iwo ni mo wa gbe ga Iwo ni mo wa gbe ga Iwo ni mo wa f'iyin fun Olorun mi to n gbe nibi giga Iwo ni mo wa gbe ga Alpha, Omega Iwo ni mo f'iyin fun o, Baba Alpha, Omega Iwo ni mo f'iyin fun o, Baba Oba to mo ibere, iwo ni Alpha, Oba to mo opin, Iwo ni Omega Iwo ni mo f'iyin fun o, Baba Iyin Re o ni tan lenu mi titi aye mi, Oluwa Alpha Omega Iwo ni mo f'iyin fun o, Baba Oloore ofe, Eleruniyin Olorun Agbaye o, mo gbe O ga Oloore ofe, Eleruniyin Olorun Agbaye, mo gbe O ga Oloore ofe, Eleruniyin Unexplainable, Indescribable, Unsearchable, Incredible Mo gbe O ga Oloore ofe, Eleruniyin Olorun Agbaye, mo gbe O ga Iyin ye Olorun wa, Oba to n gbo adura Iyin ye O o, Olorun wa Oba to n fi aanu gbadua Bi o ba se 'Wo too wa leyin mi, nibo lemi o ba wa, mi i ba ti b'aye lo Oba to n gbo adura Iyin ye Olorun wa, Oba to n gbo adura O ti n s'ise Re bo, Iwo yoo se lasepe o O ti n s'ise Re bo, Iwo yoo se lasepe O ti n s'ise Re bo laye wa, Iwo yoo se lasepe O ti n f'aanu gba mi bo Oluwa, Iwo yoo gba mi tan o, Agbanilagbatan ni O o O ti n f'aanu yo mi bo o, Oba to mu mi de'bi, Iwo yo se lasepe O ti n s'ise Re bo, Iwo yoo se lasepe O ti n s'ise Re bo laye wa, Iwo yoo se lasepe Gb'adura mi goke, Baba, gb'adura mi goke Oba Afesejin Gb'adura mi goke
Writer(s): Sola Allyson Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out