album cover
Mo Juba
663
Christian & Gospel
Mo Juba è stato pubblicato il 6 luglio 2018 da Afreal Unique Concepts come parte dell'album Imuse!
album cover
AlbumImuse!
Data di uscita6 luglio 2018
EtichettaAfreal Unique Concepts
Melodicità
Acousticità
Valence
Ballabilità
Energia
BPM87

Testi

[Chorus]
Mo juba Ọba
Mo juba Ọba
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atẹrẹrẹkariaye Ọlọrun awọn ọmọ ogun
Mo juba (Mo juba Ọba)
Mo juba rẹ (Mo juba Ọba) Ọlọrun agbaye Iwọ ni Ọba
Mo juba rẹ o (Mo juba Ọba) ko sẹlomi lẹyin rẹ, Iwọ nikan ni Ọba
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atẹrẹrẹkariaye Ọlọrun awọn ọmọ ogun
Mo juba (Mo juba Ọba)
[Verse 1]
Iba Eledumare, Ọba to ni gbogbo aye
Ẹni nla ti n bẹ lori itẹ titi lai, lai, lai
Ẹmi mi b'ọla fun Ọ, o, lat'ọgbun iṣẹda mi
Mo yi ka ọtun, mo yi t'osi, mo ba ruburubu
F'ẹni naa, alapọnle julọ, ẹni ayeraye
Iwọ lo ti n bẹ, Iwọ lo o si mọ bẹ
Lẹyin Rẹ, ko si mo, Ọba titi lai
Mo sin Ọ, mo sin Ọ, mo sin Ọ, mo sin Ọ lat'ọgbun ẹmi mi
Ẹni naa, Ọba naa, oluwosan, alaanu
Gbogbo iṣẹda ati emi, a n b'ọla fun Ọ
[Chorus]
Mo juba (Mo juba Ọba) mo juba rẹ o
Gbogbo ohun towa ninu mi juba (Mo juba Ọba) Oluwa, Ọlọrun alaanu, mo juba rẹ
Iba Eledumare, to ni gbogbo ogo
Atẹrẹrẹkariaye Ọlọrun awọn ọmọ ogun
Mo juba (Mo juba Ọba)
[Verse 2]
Iwọ ni Ọba ti o le pa'poda lailai
Ọba to ti wa ti o si mọ bẹ tititi
Aye mi yoo ma fi ibukun fun orukọ Rẹ
Ileke ọla, Ipilẹ oye, opin gbogbo ọla
Gbogbo iṣẹ Rẹ ni o ma yin Ọ, a n pe Ọ l'Ọba
Iwọ ni alaanu to f'ẹbun ṣe mi lọṣọọ
O tun fi ogo de ẹbun to fun mi lade
Ọdọ Rẹ naa ni gbogbo ogo naa n pada si Oluwa
Ẹni naa, Ọba naa, oluwosan, alaanu
Gbogbo iṣẹda ati emi, a n b'ọla fun Ọ
[Verse 3]
Gbogbo iṣẹ Rẹ ati emi o (A n b'ọla fun Ọ)
Awọn ohun taa ri at'awọn ta o ri, wọn n b'ọla fun Ọ (A n b'ọla fun Ọ)
Loke ọrun lọhun-un, lagbedemeji ilẹ ta n tẹ, ogo ni f'ookọ Rẹ (A n b'ọla fun Ọ)
Iwọ ni oni ikẹ to pọ, Ọlọla to pọ, Alaanu to pọ (A n b'ọla fun Ọ)
Ko si ede naa ni gbogbo aye ti iro ogo Rẹ ki i buyo Oluwa (A n b'ọla fun Ọ)
Hiho okun n bu ọla fun Ọ, ọsa naa n b'ọla fun Ọ, gbogbo iṣẹ ((A n b'ọla fun Ọ)
Gbogbo ede, gbogbo ijọba, lo n wariri fun orukọ Rẹ (A n b'ọla fun Ọ)
Gbogbo iṣẹ Rẹ ati emi (A n b'ọla fun Ọ)
Written by: Sola Allyson
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...