Testi

Jerryson production Ma f'ogbon wonmi Allah Ere aye o to ka r'ogbon Fi rigba lo dale Ogbon ga o ma j'agbara lo Ma f'ogbon wonmi Allah Ere aye o to ka r'ogbon Fi rigba lo dale Ogbon ga o ma j'agbara lo Jalla jalaaluhu Allah Oba ogbon tikiise poju ruju Yuhty li hikmata ma yasha Waman yuhtal hikmata faqod uhtiya khayran kethseeran Oba ogbon to npin eda logbon, o funmi niwon temi nlo Tio je nte logba pelu awujo Ogbon t'awon aye nko Ninu orin tanko emi ko Olohun lopin iyen s'odomi, modupe to kami mo Awon eyan t'araye njoko de Pe b'oriyomi ò dé aoti lelo Iyi da o j'abùkù lo o jare Ma f'ogbon wonmi Allah Ere aye o to ka r'ogbon Fi rigba lo dale Ogbon ga o ma j'agbara lo Mase je kojemi nikan, f'oriire pelu órò aye Matori adua mi naa, kowa fise pàsípàrò ikan Funmi ko f'omo iyami naa Kenikan ma woju enikan koto rina Tori ogun ebi ose dajuko, yio j'ogun ukraine lo Tebi ba bere ilara Laye je nr'ogbon fiseee Dakun jen rogbon fise Kin tun ri suuru fise Falaroka n'nu ebi ati alagidi Bosewu kon dogbon to, komiyo ninu ete gbogbo Ma f'ogbon wonmi Allah Ere aye o to ka r'ogbon Fi rigba lo dale Ogbon ga o ma j'agbara lo Ilahi bawa f'ayo ropo ibanuje awon tojepe Awon toye koje ààyò won, won nbawon s'òtá ojumo Iyawo to nkoju ogun iya oko, seripe isoro loje Ati iya oko t'iyawo o jeo gbadun omo tobi debi èrè omo Bawa segun ogun adojule Awon tonmu iru e niwa Bawa yiwon lokan pada, ao sha nife ki okun ebi o ja Irorun da, oma ju inira lo Ma f'ogbon wonmi Allah Ere aye o to ka r'ogbon Fi rigba lo dale Ogbon ga o ma j'agbara lo B'isoro bawole to eda, semope ekún loma nmuwa Ma maje a r'oro ekun mo Gbogbo adun towole to eda, semope erin loma nbade Naam Kadun ma lomo koma dekun, katewo ka fatiha f'owo boju Aye o ni dawa lokan le fekun, won o nikiwa fun ibanuje At'ogbon pelu awon ika, konise lewa lori K'ogbon ga koju ete won lo Ma f'ogbon wonmi Allah Ere aye o to ka r'ogbon Fi rigba lo dale Ogbon ga o ma j'agbara lo Ma s'ogbon mi dete (Allah) Asiso ma fikun (laye-laye) Mas'agbara d'ole (Allah) Asise ma fikun (laye-laye) Ma f'ìmò mi jóbà, Allah Àmòjù ma fikun, laye laye Ma s'oruko d'òfó, Allah Isoro ma fikun, laye laye K'alafia ma d'arun, Allah Inira ma fikun, laye laye K'ewa mi ma baje, Allah Ijàmbá ma fikun, laye laye K'aye mi ma daru, Allah K'alakoba marise, laye laye
Writer(s): Oriyomi Sanni Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out