album cover
Ogede
5,045
Fuji
Ogede was released on April 14, 2023 by DAMJAY FILMS & RECORDS as a part of the album Timeless
album cover
Release DateApril 14, 2023
LabelDAMJAY FILMS & RECORDS
Melodicness
Acousticness
Valence
Danceability
Energy
BPM136

Music Video

Music Video

Credits

PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
K1 De Ultimate
Performer
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Songwriter

Lyrics

Ìgbà tuntun ló dé
Wasiu Àyìndé o
Ọpẹ́ lo yẹ ẹrú
K1 De Ultimate
Adé orí ọ̀kín o o
Máyégún General o
Ògé dé ọlọ́jà ẹyẹ
Ògé mà mà dé ọlọ́jà ẹyẹ
Mímọ̀ọ́ ṣe kọ́ Àyìndé o
Ohun gbogbo lọ́wọ́ orí
Àṣẹ Elédùmarè ni
Mo ní ẹ wa ibi ire f’ògé sí
Ògé mà mà dé ọlọ́jà ẹyẹ
Ògé dé ọlọ́jà ẹyẹ o
(Ògé mà mà dé ọlọ́jà ẹyẹ)
Ògé dé ọlọ́jà ẹyẹ o
(Ògé mà mà dé ọlọ́jà ẹyẹ)
Àyìndé mà dé o Arábámbí
Iná lójú iná lẹ́nu
Àbàtà yẹrì yẹrì yẹrì yẹrì yẹrì
K’íṣu tó d’iyán a gún ìṣù lódó
Kí àgbàdo tó d’ògì a lọ̀ wọ́n papọ̀ o
Kí ọmọ tó wáyé ẹ̀yin èèyàn mi
Màmá pẹ̀lú bàbá ẹ̀ ni ẹ bi
Ó mà ní’hun tí ojú u wọ́n kàn o
Ògé mà ma dé ọlọ́jà ẹyẹ o
(Ògé mà ma dé ọlọ́jà ẹyẹ)
Ọmọ tó máa jẹ́ àṣàmú o
Kékeré ló ti máa ṣ’ẹnu sham sham sham sham
Iṣẹ́ là á ṣe tá a bá d’óko iṣẹ́
Ẹní mú orí ọlà wá’yé
B’ó ti já EWÉ ọlà láti ọ̀run
Á kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ná láyé kó tó rí àánú Ọlọ́hun gbà o
Kò ní ri he lórí títì dájúdájú
Ọpẹ́ ni mo mú wá lójojúmọ́ ayé
Níṣe ni èmi mà ń dúpẹ́
Ọlọ́hun Ọba ló ni mímọ̀ọ́ṣe lọ́wọ́
Àṣẹ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba ni
(Èmi mọ̀ ọ́ lóore)
Àní Ọlọ́hun Ọba ló ni mímọ̀ọ́ ṣe lọ́wọ́
Àṣẹ Ọlọ́hun Ọba ni
(Èmi mọ̀ọ́ lóore)
Orin ṣá ni ọ̀na tèmi
Mo dẹ̀ ń kọ ọ́ ní kíkan kíkan
Mò ń kọ ọ́ lójojúmọ́
Mo rí àánú Ọlọ́hun gbà o
Mo rí àánú Ọlọ́hun gbà o
Ẹgbẹ́ Àyìndé o
Ẹ jẹ́ á kà á síwájú
Wàsá kọ́ ni eré e Fújì mi
Wọ́n ń pé àwa la dé o
(Àwa la dé)
Wọ́n ń pé àwa la dé o
(Àwa la dé)
Ayé tí ẹnìkan ń yọ jẹ
(Tí ẹnìkan ń yọ jẹ)
(Ayé tí ẹnìkan ń yọ jẹ)
(Làwọ̀n kan ń jẹ ṣùà)
(Bí ẹní jẹ iṣu)
Bí èèyàn bá ṣe gbogbo ohun lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀
Á máa gbé ilé ayé jó
Inú ẹ̀ á dùn ọmọ Anífowóṣe o
(Á aláyọ̀, á lálẹ́)
Ayé tí ẹnìkan ń yọ jẹ
(Tí ẹnìkan ń yọ jẹ)
(Ayé tí ẹnìkan ń yọ jẹ)
(Làwọ̀n kan ń jẹ ṣùà)
(Bí ẹní jẹ iṣu)
Bí èèyàn bá dúpẹ́ oore Ọlọ́hun
Á gba ìmíì si
Èmi dúpẹ́ Ọlọ́hun ìgbà gbogbo
Pàápàá, oore Ọlọ́hun lórí Báyọ̀ ọmọ Ọláṣojú
Àrẹ̀mú Alága ìjọba Ìsọlọ̀ tuntun
Káàbọ̀ sí orí àléfà wàá jẹ ayé pẹ́ pẹ́ pẹ́ pẹ́
Àrẹ̀mú Adébáyọ̀ ọkọ Jùmọ̀kẹ́ o
O kú oríire Àrẹ̀mú adé
Àrẹ̀mú yọ lókèèrè
Ẹ̀ ń ṣe orí lègbélègbé
(Àbí orí ń ta yín?)
Èèyàn Sànyàolú Abibu mi
Olówóòpejò mi Kúnlé kúnlé
Ó yọ lókèèrè
Ẹ̀ ń ṣe orí lègbélègbé
(Àbí orí ń ta yín?)
Adégoróyè mi Alóyinlóhùn mi Arábámbí
Ọlásúnkànmí ọkọ Àjíkẹ́
Emmanuella Rọ́pò mi o
Ọ̀jànímògún ará ìjámọ̀
Ọmọ epo ń pọ́ ro ro ro ro ro ro
Ǹlẹ́ o, àjà ń rọ̀ dẹ̀ dẹ̀ dẹ̀
Ìtẹsì òròkí aya ti Máyégún General mi
Àrẹ̀mú yọ lókèèrè
Ẹ̀ ń ṣe orí lègbélègbé
(Àbí orí ń ta yín?)
Ṣe kínní yẹn fún mi
(Bàbá olóyè ló ń bọ́)
Ṣe kínní yẹn fún mi
(Bàbá olóyè ló ń kí)
Ijó ni ẹ bá mi jó
(Ijó ni ẹ bá mi jó)
Ijó ni ẹ bá mi jó
(Ijó ni ẹ bá mi jó)
Ijó ni ẹ bá mi jó
(Ijó ni ẹ bá mi jó)
Ah! Ṣe kínní yẹn fún mi
(Bàbá olóyè ló ń bọ́)
Mọdé yìí, ṣe kínní yẹn fún mi
(Bàbá olóyè ló ń kí)
Ṣe kínní yẹn fún mi
(Bàbá olóyè ló ń bọ́)
Ṣe kínní yẹn fún mi
(Bàbá olóyè ló ń kí)
Ní mo fi re ilé Àyìnlá Saliu ọmọ olóore
Ọkọ Mudirakatu mi Àṣàkún adé
Àna Ìyálọ́jà ní oshòdì Èjìdé mi Sikira
Sikira Alhaja mi aya Adéyanjú mi
Aya ti Ìṣọ̀lá Tesilim mi o
Sokopao mi Alhaja Sikira
Too much money mi Àyìnlá adé tèmi
Saliu Àyìnlá aláṣẹ Brazo International
Clearing and forwarding Agency mi o
Aláṣẹ Marblefield Hotel ní Oshòdì
My personal person mo kí ẹ kí ẹ
Èèyàn tèmi dáadáa ni
Ọmọ bàbá Nepa tó kú níjọ́sí
O kú ilédè bàbá ẹ
Ọmọ Alhaja Abusatu mi Àdùkẹ́ Adé mi
Títídọlá Saliu ọmọ Sanni
Ọmọ òkò ìrèsé wò-í-rà
Ko má ba à ra ẹrú k’ẹ́rú
Ẹrú k’ẹ́rú ní ń yọ olúwa rẹ lẹ́nu
Òkò ìrèsé wò-í-rà
Kó ó má ba à ra igbákígbá
Igbákígbá ní ń so lala nínú oko
Òkò ń pa ewú r’ewú
Bí ọmọ ìjẹtàdínlógún
Nílé Ajíṣọlá ọmọ kele kele ògún
Bàbá Samiatu bàbá Ọlákúnlé Junior
Bàbá Bọ́dúnrìn mi awo t’Àyìndé o
Èèyàn ta ni?
Prince Ọlámilékan ọmọ Babámúyidé
Oore kì í ya ọ̀rẹ́
Wọ́n jọ ń ṣ’ọlá ni
Wàá j’ayé pẹ́ pẹ́ pẹ́ pẹ́ pẹ́ pẹ́
Ọkọ Tinúọlá mi Bàbá Túnráyọ̀ o
Èèyàn ọmọ Wusú ní Badagry mi
Èèyàn pastor Fáṣawẹ̀ mi o
Àdúrà á máa gbà Amina
Èèyàn Dàda ọmọ Àígbè mi
Dàda olówóẹyọ
Dàda olówó dollar olówó ńlá
Fún mi ní owó ẹyọ kí n mu re’lé
Àígbè awo ti Àyìndé o
Èèyàn Alhaji Lukumonu mi ọmọ ti Amzan mi
Ọ̀yọ́ ni ilé ọmọ Ọba
Ìyẹn ọkọ lady kan Temmy mi n8 Ìjẹ̀sà
Ẹrú ọwá ọmọ obòkun ré mi
Ìjẹ̀sà ọmọ Obòkun
Temmy baby aya Lukumonu mi
Wàá j’ayé pẹ́ pẹ́ pẹ́ pẹ́
Èèyàn Ẹyẹ Sunday mi ọmọ Adéyẹmọ
Òkè Ìbàdàn nílé olúyọ̀lé o ṣeun
Asune èèyàn Sakiru dollar mi o
Ọmọ Ambali ní Ìjẹ̀bú òde
Ìyẹn ní Toronto á bá ire wá sí ilé
Èèyàn Adé Agúnbíadé mi ní bodè o
Èèyàn Tó yìn Ọlọ́hunòjẹ́ o ṣeun
Ìlọrin Àfọ̀njá Aríkurani
Mo kí ẹ kí ẹ Àjùmọ̀bí o
Èèyàn Òṣìléwù mi Akeem Ṣíwájú
Aṣíwájú Akimari mi
Bá mi tọ́jú Sharon Stone
Tọ́jú my personal assistant mi
Akọ tí ń jẹ́ Mọ̀ǹsúrù mi ọmọ Martins
Ọmọ Tóò Much Money
Mo kí ẹ kí ẹ Mọ̀ǹsúrù Akọ
Oore ṣíṣe Íbúró
(Lo fi jẹ́ ọmọ olóore)
Oore ṣíṣe Íbúró
(Lo fi jẹ́ ọmọ olóore)
Ká má fi ojú pa ẹnìkan rẹ
(Lo fi jẹ́ ọmọ olóore)
Àánú lójojúmọ́
(Lo fi jẹ́ ọmọ olóore)
Ẹni tó bá ṣe shior ẹ Àyìnlá o
(Olúwa á ṣe shior wọn)
(Ní ìgbà bí i fifty ó)
Ẹni tó bá ṣe shior ẹ Àyìnlá o
(Olúwa á ṣe shior wọn)
(Ní ìgbà bí i fifty ó)
Ọmọ Agara onílẹ̀gbalẹ̀
(Íbúró too much mi ọkọ Mudiraka)
Ọmọ Agara onílẹ̀gbalẹ̀
(Íbúró too much mi ọkọ Mudiraka)
Àyìnlá ọmọ bàbá Nepa
(Íbúró too much mi ọkọ Mudiraka)
Agara onílẹ̀gbalẹ̀
(Íbúró too much mi ọkọ Mudiraka)
Agara onílẹ̀gbalẹ̀
(Íbúró too much mi ọkọ Mudiraka)
Mi ò lè kọjá lọ ní oshodi
Kí n má ya ilé e tì ẹ
Ayédáadé mi Àyìndé o
Alága National Union Lagos State Chapter
Mo kí ẹ kí ẹ
Mc Musiliu Olúọmọ
Èkó motor hun ló ń jẹ́
Èèyàn Kúdẹrẹ́tì mi Sulele ọlọ́rẹ o
Súlè Maito
Ọjọ́apasà mi Àtàndá adé
Èèyàn baby boy bàbá Èbúté
Walimusitapha mi Sego Adékúnlé
Mo kí ẹ kí ẹ Àyìndé Ayédáadé
Àjọṣe wa ò ní bàjẹ́ Kọ́lá Ọlọ́hun
Àdúà á máa gbà o
Èkó motor ló ń jẹ́
Àyìndé mi Musiliu
(Ayédáadé)
Èkó motor ló ń jẹ́
Àyìndé mi Musiliu
(Ayédáadé)
Alága National Union
(Ayédáadé)
Ní Lagos State Àyìndé mi Musiliu
(Ayédáadé)
Àyìndé mi Musiliu
(Ayédáadé)
Àyìndé mi Musiliu o
(Ayédáadé)
Written by: Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...