album cover
Aje
2,130
African
Aje was released on April 14, 2023 by DAMJAY FILMS & RECORDS as a part of the album Timeless
album cover
Release DateApril 14, 2023
LabelDAMJAY FILMS & RECORDS
Melodicness
Acousticness
Valence
Danceability
Energy
BPM130

Credits

PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
K1 De Ultimate
Performer
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Songwriter

Lyrics

Ah ah
Mo bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun Ọba
Gbogbo ohun to bá máa ṣe fún mi
Àlàáfíà ni kó bọ́ sí nínú ìrọ̀rùn
Kí n lè r’ọ́pẹ́ dá Ọlọ́hun
Thank you God
Ojú ló mọ ohun tó yó’nú
Ìdodo tẹ́ ẹ rí yẹn òhun ni ìdájì ara
(Ìbẹ̀rù Ọlọ́hun)
(Ṣèbí òhun ló yẹ ká ní)
Ọlọ́hun o gbọ́ o tì ẹ ni mo ṣe
Èmi ò dẹ̀ ní ẹlòmíràn tí n máa ké sí lójoojúmọ́
Elétí gbáròyé Ọlọ́hun Ọba ló ń bá mi ṣé
Ojú ló mọ ohun tó yó inú
Ìdodo tẹ́ ẹ rí yẹn òhun ni ìdájì ara
(Ìbẹ̀rù Ọlọ́hun)
(Ṣèbí òhun ló yẹ ká ní)
Ìrìnkèrindò ọmọ ẹ̀dá láyé o
Àbí nítorí á dà á dà kọ́
Bí a bá wá da gbogbo ohun náà tán
Àyìndé kí la ó fi rà o
Èèyàn Tó ń lọ sí Ìbàdàn tó ń sáré
Ẹ bá mi ké pe onítọ̀hún
Asúré tete kan ò ní kọjá ilé
Ìran asùngbẹ̀rẹ̀ kan ò ní sùn s’ọ́nà
Ọmọ Anífowóṣe o
Ká ṣe sùúrù láyé n8bí
Ojú ló mọ ohun tó yó’nú
Ìdodo tẹ́ ẹ rí yẹn òhun ni ìdájì ara
(Ìbẹ̀rù Ọlọ́hun)
(Ṣèbí òhun ló yẹ ká ní)
Èèyàn tó bá gbà fún Ọlọ́hun Ọba
Á lọ́lá, á lọ́là, á láyọ̀
Nínú àlàáfíà gbogbo ohun tó máa ṣe láyé
Mo wá ń bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun
Ẹ̀bẹ̀ ni mo fi ṣe
Ọlọ́hun kẹ́ mi gẹ̀ mí
Ṣe ire ọwọ́ ẹ fún mi arábámbí
Gbogbo èyí tó wà lápò
Kó bá mi di ọjọ́ alẹ́
Àdúà wá ti gbà Amin
Ọmọ tó máa jẹ́ àṣàmú o
Ṣé àti kékeré ni á ti ṣe ẹnu ẹ̀ ṣámú
K1 De Ultimate
Àyìndé bàbá ni bàbá ń jẹ́
Ojú ló mọ ohun tó yó’nú
Ìdodo tẹ́ ẹ rí yẹn òhun ni ìdájì ara
(Ìbẹ̀rù Ọlọ́hun)
(Ṣèbí òhun ló yẹ ká ní)
Má a gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Kolaq alágbo ọkọ Miwá baby
Àdúà rẹ ti gbà o ti r’ójú ọlá
Èèyàn ti General mi ọmọ Atóyegbé mi
Ọmọ ọmọ aláàánú mi ní Ẹ̀pẹ́ ilé
Àní ló mọ ohun tó yó’nú
Ìdodo tẹ́ ẹ rí yẹn òhun ni ìdájì ara
(Ìbẹ̀rù Ọlọ́hun)
(Ṣèbí òhun ló yẹ ká ní)
Orí mi mọ́gbọ́láhàn
(Kò ní burú)
(Arabic rendition)
Ẹrú n túbá
Orí mi mọ́gbọ́láhàn
(Kò ní burú)
(Arabic rendition)
Ẹrú ń túbá
Ajé ń bá mi sùn
Ajé ń bá mi jí
Ajé má fi mí sílẹ̀
Mo fẹ́ ká jọ máa gbé
(Ajé ń bá mi sùn)
(Ajé ń bá mi jí)
(Ajé má fi mí sílẹ̀)
(Mo fẹ́ ká jọ máa gbé)
Wasiu Àyìndé o o
Àní Ajé ń bá mi sùn
Ajé ń bá mi jí
Ajé má fi mí sílẹ̀
Mo fẹ́ ká jọ máa gbé
(Ajé ń bá mi sùn)
(Ajé ń bá mi jí)
(Ajé má fi mí sílẹ̀)
(Mo fẹ́ ká jọ máa gbé)
Gbogbo ìgbà
Kí n máa r’ówó pè ráńṣẹ́ Ọlọ́hun Ọba
Àyìndé kí n má padà di atọrọjẹ
Àní Ajé ń bá mi sùn
Ajé ń bá mi jí
K’ájé má fi mí sílẹ̀
Mo fẹ́ ká jọ máa gbé
(Ajé ń bá mi sùn)
(Ajé ń bá mi jí)
(Ajé má fi mí sílẹ̀)
(Mo fẹ́ ká jọ máa gbé)
Máa gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Alhaja Yaofeek mi Ọláolúwakìítán
Àlàó ẹ bá mi kí ọmọ Williams tèmi
Aláṣẹ King Maleek Estate
Àdúà ẹ́ ti gbà Àlàó
Ọkọ Alhaja Morufatu Abíọlá
Àyìnkẹ́ adé mi Norufa
Ọkọ Rashidatu mi Ayọ̀ọlá o káre
Èjìrẹ́ ọmọ méjì mi
Àyìnkẹ́ adé mi ní ìlú Ìlọrin
Ọlá bàbá Ọlájùmọ̀kẹ́, bàbá Ọláńrewájú
Bàbá Debby mi o seun
Ìrọ̀rùnọlá bàbá Maleek ní Saudi
Àdúà ẹ ti gbà Àlàó
Ọmọlọlá Nancy yìí o ṣé
Èèyàn K1 De Ultimate mi Àlàó
Awo ti Ìyàndá Kasime
Mo kí ẹ kí ẹ Adémọ́lá
Ọjọrá àgbasà mi
Aláṣẹ Adekaz Hotel
Ọmọ Àtọ̀kẹ́ adé mi bàbá Àtọ́kẹ́
Ọkọ Adijatu Kubura Àríkẹ́ adé
Ọkọ Aishatu mi Vicky mi
O káre Àbẹ̀ní o
Ọkọ Àdùkẹ́ Wasilatu
Ọkọ ti Ayọ̀mikùlẹ́hìn
Mo kí ẹ kí ẹ o Alhaja Nura
Ìrọ̀rùnọlá bàbá Tekbir bàbá Ṣemílóore
Ìyàndá Kasime bàbá Tọ̀míwá
Àní ajéń bá mi sùn
Ajé ń bá mi jí
K’ájé má fi mí sílẹ̀
Mo fẹ́ ká jọ máa gbé
(Ajé ń bá mi sùn)
(Ajé ń bá mi jí)
(Ajé má fi mí sílẹ̀)
(Mo fẹ́ ká jọ máa gbé)
Èèyàn Alhaji Lukumonu mi
Ọmọ́gbọ́láhàn mi ọmọ ti Ìdòwú
Aláṣẹ The Skin Hotel
Ọkọ Falilatu Ọlápéjú
Àdùnní adé mi Falila
Bàbá Faida mi Kòfówórọlá
Àjọkẹ́ mi ní ìlú Canada
Wàá bá ire wálé
Bàbá ti Ọlámilékan Fawaz mi
Bàbá Àbíkẹ́ mi Fatima
Mr Skin bàbá Táyélolú mi
Bàbá ọmọ méjì
Èjìrẹ́ mi Kẹ́hìndé o
Ọlá bàbá Faruk Ọlámidé mi Àkànní
Àdúà ẹ ti gbà gbogbo wa
Má a gbọ́ bí mo ṣe ń wí
Ọmọ Jẹ́nrádé Wasiu ní Olúyọ̀lé ilé
Èèyàn Adégoróyè mi Arábámbí mi
Alhaji Wasiu ọmọ Jẹ́nrádé
Bó o bá jayé títí
Ìdun ní Ayẹ́yẹ́ kó o ma bá mi ki
Bàbá Aishatu mi awo Arábámbí mi
Àdúà ti gbà Ìdun
Bí mo bá ń lọ
Ire máa bá mi lọ
Bí mo bá ń bọ̀
Ire máa bá mi bọ̀
Àti ọ̀tún àti òsì
Ire má padà lẹ́yìn mi
(Bí mo bá ń lọ)
(Ire máa bá mi lọ)
(Bí mo bá ń bọ̀)
(Ire máa bá mi bọ̀)
(Àti ọ̀tún àti òsì)
(Ire má padà lẹ́yìn mi)
Ìdun l’Áyẹ́yẹ́
Èèyàn K1 De Ultimate Ìdun
Ọlá bàbá Ai ó ń gbọ́ o
Wese ọmọ Jẹ́nrádé
Bí mo bá ń lọ
Ire máa bá mi lọ
Mo ní bí mo bá ń bọ̀
Ire máa bá mi bọ̀
Àti ọ̀tún àti òsì
Ire má padà lẹ́yìn mi
(Bí mo bá ń lọ)
(Ire máa bá mi lọ)
(Bí mo bá ń bọ̀)
(Ire máa bá mi bọ̀)
(Àti ọ̀tún àti òsì)
(Ire má padà lẹ́yìn mi)
Àti ọ̀tún àti òsì
(Ire má padà lẹ́yìn mi)
Àti ọ̀tún àti òsì
(Ire má padà lẹ́yìn mi)
Ajé ń bá mi
(Ajé ń bá mi gbé)
Ajé ń bá mi
(Ajé ń bá mi gbé)
Mo dúpẹ́ Ọlọ́hun
(Ajé ń bá mi gbé)
Mo mà dúpẹ́ Ọlọ́hun o
(Ajé ń bá mi gbé)
Mo dúpẹ́ Ọlọ́hun
(Ajé ń bá mi gbé)
Written by: Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...