album cover
Balablue
1,887
African
Balablue was released on April 14, 2023 by DAMJAY FILMS & RECORDS as a part of the album Timeless
album cover
Release DateApril 14, 2023
LabelDAMJAY FILMS & RECORDS
Melodicness
Acousticness
Valence
Danceability
Energy
BPM141

Credits

PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
K1 De Ultimate
Performer
9ice
9ice
Performer
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Drums, Keyboards
COMPOSITION & LYRICS
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Songwriter

Lyrics

Ọmọ Nigeria
(Aṣíwájú ti dé)
(Àwá gbà pé oríire ti dé)
Ah ah
Bẹ́ẹ̀ náà ló rí
Ọmọ Nigeria
(Aṣíwájú ti dé)
(Àwá gbà pé oríire ti dé)
Gbogbo ọmọ Nigeria
Ìmọ́lẹ̀ẹ dé, ó jọba lórí òkùnkùn
Ẹní m’ọ̀nà ló yẹ ká tẹ̀lé
Àkànbí Aṣíwájú pẹ̀lú Shettima
Wọ́n ti mú ìgbà rere d’ẹ̀yìn bọ̀ o
Gbogbo àdúà tá a ṣe lórí Nigeria
Kó má ṣe ṣubú
Ọlọ́hun Ọba gbọ́
Ọlọ́hun Ọbá gbà á
Èsì Election ní Nigeria ẹ ẹ̀ rí ibi tó já sí
Ọmọ Nigeria
(Aṣíwájú ti dé)
(Àwá gbà pé oríire ti dé)
Gbogbo ìgbà tí mo bá ń bọ̀
Aya tẹbí t’ọmọ t’ará láàrin ìlú
Á máa kó s’ókè
Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìlú
Tí wọ́n wà lókè òkun o
Àwọn náà aya wọn á máa kó s’ókè
Lórí ẹbí wọn
Ṣùgbọ́n a dúpẹ́, a dúpẹ́ a t’ọ́pẹ́ dá
Gbogbo ọmọ Nigeria a mà kú oríire àsìkò yìí o
Especially àwọn Youth nílùú Nigeria
Ọ̀dọ́ ìlú, ẹ ti f’ẹ̀hónú hàn Àyìndé
Ẹ ti sọ ohun tẹ́ ẹ fẹ́
O sure ju Bida dẹ̀ ti gbọ́
Òun náà ti f’èsì
Ó ní gbogbo ohun tí ọ̀dọ́ bá ń fẹ́ ní Nigeria
Ó ní ó ti di bíbọ́si
Ẹ ẹ̀ ri bí
Ọmọ Nigeria
(Aṣíwájú ti dé)
(Àwá gbà pé oríire ti dé)
Ọ̀rọ̀ tó ń dùn gbogbo ará ìlú
Ká a sùn ká má dijú
Kí àyà a wa máa ká s’ókè
Ká a yàn lọ, ká a yan bọ̀
Lórí iṣẹ́ lórí jíjẹ mímu o
Àkànbí Aṣíwájú
Ó ní wàhálà wa ti dópin nílẹ̀ yìí
Torí pé ẹní m’ọ̀nà òun ló yẹ ká tẹ̀lé
Àkànbí mà ti m’ọ̀nà tipẹ́tipẹ̀
Ó ti k’ọ́ṣẹ́ láṣepé
Láti Ọwọ́ Awólọ́wọ̀ àti MK mi Moshood Abíọ́lá
Ó ní ọ̀rọ wọ́n ń ti ilé ìwé University
Ó ní òun ti fi igi ọ̀hún ré nílẹ̀ yìí
Irú ẹ̀ ò tún ṣẹlẹ̀ mọ́
Ká a ti ilé ìwé
Kí àwọn ọmọ má rí ibi gbà lọ o
Àkànbí Aṣíwájú ó ní ó ti lọ gbéré gbére
Ọlọ́hun á fún ẹ ṣe Àkànbí o
Àbò tó péye fún gbogbo ará ìlú
Ó ní t’onílé t’àlejò
Ẹ lọ fọkàn balẹ̀ o
Ó ní òun di servant fún gbogbo ìlú
Yàtọ̀ sí pé òun jẹ leader t’oníkálukú
Ó ní iṣẹ́ ẹ wa ló jẹ òun lógún
A wá ń gbà á ní àdúà
Ìwọ pẹ̀lú Shettima mi Àkànbí Aṣíwájú
Ọlọ́hun á fún ẹ ṣe Àkànbí o
Àdúà ló yẹ ká a gbà fún àwọn olórí i wa
Kí wọ́n le máa ṣe dáadáa
Bí wọ́n bá ti ń ri ṣe inú wa á dùn
Ọ̀rọ kò s’ówó nílẹ̀ yìí
Ìyẹn ti di’hun à fi bú
Tẹrú t’ọmọ ká a ma rìn
Ká a ma yanfanda
A mà dúpẹ́ Ọlọ́hun
Ìrànlọ́wọ́ fún gbogbo oníṣòwò
Àwọn àgbẹ̀ àrọko b’ọ́dun dé
Gbogbo farmers across Nigeria
Let all of us start to rejoice
Àkànbí Shettima, wọ́n ti ní solution
Àyìndé Wasiu sí gbogbo nǹkan wa
Aṣíwájú Shettima ló sọ̀rọ̀ kan fún mi
Aṣíwájú Shettima ló sọ̀rọ̀ kan fún mi sẹ́ o
(Don't lose hope)
(We are almost there)
(Better days ahead)
(Surely, we shall be there soon)
Aṣíwájú Shettima ló sọ̀rọ̀ kan fún mi sẹ́ o
(Don't lose hope)
(We are almost there)
(Better days ahead)
(Surely, we shall be there soon)
On your mandate we all go stand o
Tinubú plus Shettima
(Eh eh eh)
(On you we rest our hope o)
(On your mandate we all go stand)
On your mandate we all go stand o
Aṣíwájú!
Tinubú plus Shettima
(Eh eh eh)
(On you we rest our hope o)
(On your mandate we all go stand)
Odó idẹ kì í fọ́
Odó idẹ kì í ya
Odó idẹ kì í fọ́
Odó idẹ kì í ya
Kí wọ́n má mà d’áṣà pálapàla
Odó idẹ kì í ya o
Odó idẹ kì í fọ́
Odó idẹ kì í ya
Odó idẹ kì í fọ́
Odó idẹ kì í ya
Kí wọ́n má mà d’áṣà pálapàla
Odó idẹ kì í ya o
Odó idẹ
Odó idẹ
(Odó idẹ)
(Odó idẹ)
Odó idẹ
Odó idẹ
(Odó idẹ)
(Odó idẹ)
Ìjẹ tí ẹ jẹ tẹ̀tẹ̀
Ẹ má jẹ dágunró
Ìjẹ tí ẹ jẹ tẹ̀tẹ̀
Ẹ má jẹ dágunró
Ọ̀tafà yídó b’orí
Gbémilékè wọn
Bo ṣe ṣẹ́gun fún Àkànbí
Ọmọ olódó idẹ
Mo tọ́jú 25 percent
Mo gbé wọn ní handicap
Ọyá mi ń lé winning
Later later ọmọ
(Wọ́n succumb ni)
Ìjẹ tí ẹ jẹ tẹ̀tẹ̀
Ẹ má jẹ dágunró
Dágunró yẹn kò ṣe é jẹ Àyìndé
Àkànbí alágbára mẹ́ta lẹ̀ ń wò yìí
Agbára gbogbo ilẹ̀ Yorùbá
Agbára Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ mi
Agbára Mko Abíọ́lá
Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lára ìwọ nìkan
(Òhun ló gbé ẹ ró o alákànbí ó)
Alágbára mẹ́ta lẹ̀ ń wò yìí, Àkànbí
Agbára gbogbo ilẹ̀ Yorùbá
Agbára Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ mi
Agbára Mko Abíọ́lá
Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lára ìwọ nìkan
(Òhun ló gbé ẹ ró o alákànbí o)
Aṣíwájú tí ẹ̀ ń wò yìí
(Ọmọ ayé ni)
Àkànbí tí ẹ ń wò yìí
(Ọmọ ayé ni)
Ọmọ ayé ni
(Ọmọ ayé ni)
Ọmọ ayé ni
(Ọmọ ayé ni)
Àkànbí tí ẹ ń wò yìí
(Ọmọ ayé ni)
Ẹni tí à ń wí ti dé
Àní ẹni tí à ń wí ti dé
Fún ìlọsíwájú Nigeria o
Ẹni tí à ń wí ti dé
Àkànbí Bọ́lá ọmọ Tinubú
(Ẹni t’a á wí ti dé)
T’arúgbó t’omidan
T’ọkùnrin T’obìnrin
T’àgbà t’ọmọdé nílẹ̀ yìí
Ẹ má mikàn
Ẹ dúró wam wam wam wam
Tí Hausa ti Igbo pẹ̀lú Yorùbá wá
Gbogbo Nigeria lápapọ̀
United we stand
Divided we fall
Stand well well Àyìndé mọ́gbọ́láhàn
Ẹni tí à ń wí ti dé
Ẹni tí à ń wí ti dé
Fún ìlọsíwájú Nigeria o
Alákànbí Tinubú
(Ẹni t’a á wí ti dé)
Ọlọ́hun Ọba ti gbọ́ o
Ó gbọ́ àdúà wa
(Ẹni t’a á wí ti dé)
Àní Ọlọ́hun obá gbọ́ ó gbọ́ àdúà wa
(Ẹni t’a á wí ti dé)
Balablue Bulaba
Ọlọ́hun ọbá gba àdúà wa
Nílùú Nigeria Àyìndé
(Ẹni t’a á wí ti dé)
Balablue
Bulaba
Bulaba
Gbọ́ ná!
Àkànbí o jù wọ́n lọ
(Ma wò wọn níran)
O jù wọ́n lọ
(Ma wò wọ́ níran)
(Ma wò wọ́ níran)
Àkànbí jù wọ́n lọ
(Ma wò wọ́ níran)
Ọ̀rọ́ kò sí epo nílẹ̀ yii
Ọ̀rọ̀ owó o dollar ń lọ sókè o
Ó ti di ìtàn ní Nigeria Àyìndé
Gbogbo nǹkan yó padà di ẹ̀dínwó
Security ní ìlú Nigeria
Ó sure Ọlọ́hun Àkànbí
M’ójú tó ìyẹn fún wa o
Alákànbí Aṣíwájú
(Ẹni t’a á wí ti dé)
Ọ̀rọ̀ security tí à ń sọ
M’ójú tó ìyẹn fún wa o
Alákànbí o gbọ́
(Ẹni t’a á wí ti dé)
Written by: Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...