album cover
Democracy
18,162
Hip-Hop/Rap
Democracy was released on December 19, 2010 by DMCE as a part of the album Democracy - Single
album cover
Most Popular
Past 7 Days
00:35 - 00:45
Democracy was discovered most frequently at around 35 seconds into the song during the past week
00:00
00:35
00:50
05:10
00:00
05:26

Music Video

Music Video

Credits

PERFORMING ARTISTS
Dagrin
Dagrin
Performer
Oladapo Olaitan Olaonipekun
Oladapo Olaitan Olaonipekun
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Oladapo Olaitan Olaonipekun
Oladapo Olaitan Olaonipekun
Composer, Lyrics

Lyrics

[Verse 1]
Corruption ti hit nation
Gbogbo wa la n live in desperation
Tori ẹ ni mo ṣe n drink medication
Fun protection against starvation pẹlu corruption
Tori generation yii, a need salvation
Through a strong constitution
Ninu studio, owo nla la fi n book session
Ẹ jọ ẹ stop sensation
A need action ko n ṣe prosecution
Free Fair pẹlu alaafia ninu nation
Ẹ gbọ nnkan ti mo fẹ sọ eleyii o n ṣe body vibration
[Verse 2]
Nigeria ni mo ti ri tọlọpaa ma n tọrọ bara
Nitori twenty naira wọn le fẹ ba ẹ fa a ya
Agbero maa n fagidi gba kala lọwọ driver
Ẹ ẹ ri nnkan kan ṣe si, ẹyin ijọba ẹ kala
Gbogbo owo tẹ ti gbemi lawọn ọmọ ọmọ yin maa bi
Ẹ ẹ ri bawọn ara ilu ṣe n pariwo, ebi!
To ba ri life ti talika n live ni Birnin Kebbi
Gbogbo yin patapata l'Ọlọrun maa da lẹbi
A ranmọ lọ si school, ko ni si textbook
Ẹ dẹ promise pe ẹ maa fun wa ni free education
Ki lo n jẹ bẹẹ? Owo nla ma la fi n s'admission
Ẹ dẹ ti ko gbogbo awọn omọ ti yin kuro ninu nation
A ti igba ti mo ti n kọriin, mi o ni money
Ẹ tiẹ ki n sọrọ rara nipa music industry
Economically, agidi la fi n ra breadi
Ta lo sọ pe President o ki n fine ninu telly?
Ẹ ẹ mo ju kẹ sọrọ petrol, pẹlu football
A tigba ta dẹ ti n gba World Cup, a a gba cup
O ga o! Boya gan-an la ti ẹ gba second
Awọn yẹn naa, wọn a maa play ball bi alakan
Graduate ma ma waṣẹ, gbogbo bata ẹ a jẹ
A yẹ sẹgbẹ, everywhere ko si employment
Ẹni to ti n kọle tẹlẹ, ko le ra cement
Increase ni rent, decrease ni salary payment
[Chorus]
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin pe kẹ ma dibo
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin pe kẹ ma dibo
[Verse 3]
Awọn eeyan n ṣiṣẹ, wọn n gbe ninu iṣẹ
Awọn elomii, nitori owo, wọn ti gbẹṣẹ
Awọn elomii n gbowo ita, nitori wọn le ju ẹṣẹ
Nigba to jẹ awọn ijọba gan-an, wọn o pese iṣẹ
Wa a lọ si university, wa a ṣe tan, wa a gba pali
Peẹu pali ẹ, wa tun ma a waṣẹ kaakakiri
Gbogbo ibi to ba lọ, wọn a ni ko si vacancies
Gbogbo kini yẹn, o ma ma fun ẹ ni headache
Awọn ẹlomii n jale tori ko si iṣẹ nigboro
Economically, most obinrin ti daṣẹwo
O ga o! Ko dẹ n ṣẹjọ elomii tẹ ba ro
Ṣugbọn aṣọ yellow ti di white, lọwọ o lilo
Ijọba, ẹ wa na, hmm hmm ẹ duro na
O ga o ẹẹkan loṣu la ma n ni ina
O n happen all over Nigeria, pẹlu Kaduna
Minna, gbogbo yin tẹ n balujẹ lẹ ma gbina
Aimọye titi ti o jẹ pe mọto o le gbabẹ
Lọ s'under bridge l'Oshodi, gbogbo ibẹ ti bajẹ
Tojo ba rọ, gbogbo ibẹ yẹn maa di pẹṣẹnpẹṣẹ
To ba ya, a si maa gbọkọ oju omi kọja n'bẹ
Gbogbo promise tẹ make, irọ lo wa n'bẹ
Ṣebi ẹyin naa, ẹ ma n travel lọ si Yankee
Ẹ ri bi titi wọn pẹlu economy wọn ṣe ri?
Ẹyin kan n lọ sibẹ, ẹ kan lọ n ṣe faaji
Gbogbo nnkan lawọn ijọba yii fi niwa lara
Ko dẹ ri bẹẹ nigba ta kọkọ gbominira
But nigba ti awọn Big Boss ti take over
Gbogbo owo wa patapata l'ọn fi n da agbada
Nigeria, gbogbo wa la n fori faya
A tọmọde a tagbalaba, pẹlu tọkọ taya
Baba, mama, pẹlu awọn ọmọ mẹfa ma sun sinu yara
Ẹyọ kan, bawo l'ọn ṣe ni maa lalakala?
[Chorus]
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin pe kẹ ma dibo
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin wi pe kẹ ma dibo
[Verse 4]
Awọn eeyan maa n ni Nigeria, Giant of Africa
Lọ wo bi economy wọn ṣe better ni South Africa
Ghana celebrate ten years ti wọn ti ni ina, t'ọn o tan atupa
Ti ti yin ẹ mọ ju kẹ soge, kẹ tun wọ agbada
Igba kan l'ọn maa n ko awọn were loju titi
Awọn were maa n rin kiri pẹlu awọn eeyan gidi
Nisinyin, awọn were, wọn o l'identity
Local Government kan, o le pade were fifty
Ki lo de? Awọn olowo nikan lo n ṣoge
Awọn ọmọ yin, pẹlu awọn iyawo yin, wọn n gbe gele
Ẹ n gbe fila Democracy alagbada
O ga o owo gbogbo wa lẹ fi n yata
National ID Card, owo la fi n register
A o ri nnkan kan ẹ da passport wa pada
Ẹ n waste time ọmọde pẹlu agbalagba
Ẹ ṣe o ẹ ranti pe Ọlọrun wa
Igba ta gbọ National ID Card, inu wa dun
A ṣ'ọn n dọgbọn, wọn fẹ ki ọba wọle
Ọba ti wọle, agidi la fi n sanwo ile
School ma strike, one year, ṣe iyẹn la fẹ pe l'holiday?
Ẹ ẹ sanwo awọn oṣiṣẹ, ẹ ranti pawọn naa lọmọ n'le
Awa la ni petrol, ki lo de ti petrol o flow?
Ẹ n gbowo le e lojoojumọ, ki lo ṣe yin o?
T'Ọlọrun ba binu, gbogbo yin ni petrol maa jo
Ṣe democracy alagbada leleyii tabi ṣinmi?
Ẹ ranti pe most people lo tẹka fun yin
A a le ra Maclean, pako la maa fi n fọyin
Ki lo ṣe yin? Eeyan ṣa lawọn Bill Clinton
O o le ji lọjọ kan, ko sọ pe o fẹ jẹyan
Lai ṣọjọ Sunday garri ike kan gan-an ti wọn
Alagbara lẹni to ba ra rice De Rica kan
O pay mi ki n kuro ni Nigeria, ki n salọ s'Abidjan
[Chorus]
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin pe kẹ ma dibo
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin wi pe kẹ ma dibo
[Chorus]
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin pe kẹ ma dibo
Ṣe democracy leleyii abi crazy demo?
Oluwa ṣaanu wa dakun ma ma jẹ ka jẹgo
Ba wa laju awọn ijọba ko to di quarter-to
Mo dẹ pariwo titi fun yin wi pe kẹ ma dibo
Written by: Oladapo Olaitan Olaonipekun
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...