Credits

PERFORMING ARTISTS
EmmaOMG
EmmaOMG
Performer
D'guitroman
D'guitroman
Lead Guitar
Otedola Oredolapo
Otedola Oredolapo
Rhythm Guitar
COMPOSITION & LYRICS
Emmanuel Edunjobi
Emmanuel Edunjobi
Songwriter
PRODUCTION & ENGINEERING
EmmaOMG
EmmaOMG
Producer
Soundmindpro
Soundmindpro
Mastering Engineer

Lyrics

[Intro]
Oluwa tobi ni Sioni, O si jọba lori gbogbo orilẹ-ede
Jẹ ki wọn yin orukọ rẹ ti o tobi ti o si lẹru, oh my God
[Verse 1]
Gbogbo aye n wariri ni oruko rẹ, wọn n kọrin
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Awọn ọrun naa n ṣẹlẹrii, wọn n foribalẹ niwaju itẹ rẹ, wọn sọ wi pe
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Wọn ni ẹ ti tobi to ooo, Oluwa wa
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Wọn ni ẹ ti tobi to ooo, Oluwa wa o
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Awọn oke nla nla wọn n foribalẹ o tori iwọ ni Ogo ati Ọla ju oke nla ikogun wọnni lọ o
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Iwọ ti Ọlọrun ji dide kuro ninu oku, lati gba wa kuro ninu ibinu ti n bọ o
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Iwọ Oluwa Ọlọrun to n gbe laarin awọn Kerubu, to pọ ni ipa ati agbara o, eh eh
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Ani gbogbo aye n wariri ni orukọ rẹ, wọn n kọrin
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Awọn ọrun naa n ṣẹlẹrii, wọn n foribalẹ niwaju itẹ rẹ
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Wọn ni ẹ ti tobi to ooo, Oluwa wa
Ẹ ti tobi to o, Jesu
[Verse 2]
Ipẹkun ọla, ipẹkun iye eh eh, ẹ ti tobi to ooo
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Ireti wa o, Ẹri wa o, ẹ ti tobi to ooo
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Itansan ọrun to mọlẹ roro roro roro, ẹ ti tobi to, aye atọrun n bọ o o
Ẹ ti tobi to o (Wọn juba fọba Ajunilọ), Jesu (Wọn foribalẹ fọba Ajunilọ)
Jordani ri o o pada sẹyin, okun ri ọ, o sa, ẹ ti tobi to Olodumare
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Abetilukara bi ajere, Baba mi agba oye, ẹ ti tobi to
Ẹ ti tobi to o, Jesu
[Verse 3]
Tori naa, gbogbo aye n wariri ni oruko rẹ, wọn n kọrin
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Awọn ọrun n sẹlẹrii, wọn n foribalẹ niwaju itẹ rẹ
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Wọn ni ẹ ti tobi to o, Oluwa wa
Ẹ ti tobi to o, Jesu
[Verse 4]
Gbongbo idile Jese, Jesu ọkan mi foribalẹ o, o sọ wi pe
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Ipekun ọla, Ipekun ọrọ, Ipẹkun agbara o, ẹ ti tobi to oo, ẹ ti tobi to oo
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Ọla ati ọla nla ni o wa niwaju rẹ, ipa ati ẹwa n bẹ ninu ibi mimọ rẹ o
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Akaikatan o, Abuubutan o, Atobiloye, egbe lẹyin ẹni a n daloro oo, ẹ ti, ẹ ti, ẹ ti tobi to o
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Jesu, gbogbo aye n wariri ni oruko rẹ, wọn n kọrin
Ẹ ti tobi to o, Jesu
Awọn ọrun naa n ṣẹlẹrii, wọn n foribalẹ niwaju itẹ rẹ o eh
Ẹ ti tobi to o, Jesu
[Verse 5]
Wọn juba fajunilọ o (Ajunilọ)
Ẹ ba n juba fajunilọ eh
Ẹ ba n ṣeba fajunilọ o
Ẹ ba n gboṣuba fajunilọ
Ẹ ba n juba fajunilọ
Ẹ ba n gboṣuba fajunilọ
Ẹ ba mi juba fajunilọ
Ẹ ba mi juba fajunilọ
Ẹ ba mi juba fajunilọ
Ẹ ba n gboṣuba fajunilọ
Ẹ ba mi juba fajunilọ (Fajunilọ)
Ẹ ba mi juba fajunilọ
[Outro]
Ani gbogbo aye n wariri ni orukọ rẹ, wọn n kọrin
Ẹ ti tobi to o, Jesu, oh my God
Written by: Emmanuel Edunjobi
instagramSharePathic_arrow_out

Loading...