Credits
PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
Performer
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Drums
COMPOSITION & LYRICS
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Songwriter
Lyrics
Torí pé ní 1970, mi ò le gbàgbé
Èmi wà l’Ansarudeen college ní ìsọlọ̀
A dẹ̀ máa ń ṣe inter school exchange
Lórí sport, lórí Quiz competition
Christy Apostolic ní gbogbo àgbègbè yìí
Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn mi ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni
Ọlọ́hun Ọba o ṣé
Gbogbo àwa tó bá ní Opportunity láti gba ibí yìí kọjá
Wọ́n ti d’ẹni bí ẹni o, wọ́n ti d’ènìyàn bí ènìyàn
Senior Advocate of Nigeria wọ́n ti d’adájọ́
Wọ́n ti d’engineer
Gbogbo discipline lóríṣiríṣi Ọmọ́gbọ́láhàn wọ́n ti ṣe
Wọn ò dẹ̀ gbàgbé ìpìlẹ̀, wọn ò gbàgbé ibí
Ọlọ́hun ò ní gbàgbé gbogbo wa congratulation mo ki yín
Ìlú ìpẹ́ru kò bàjẹ́ láti ayé ìwáṣẹ̀
Gbogbo Rẹ́mọ Division gbogbo Ìjẹ̀bú Province láti ayé ìwáṣẹ̀
Àyìndé Wasiu a kú oríire
Ẹ̀yin tí ẹ bá ń wò wá nílé
Ẹ̀yin tí ẹ ti ṣe irú ẹ̀ àti ẹ̀yin èwe ìwòyí
Ẹ mọ̀ pé iṣẹ́ ń bẹ lọ́wọ́ yín torí ọjọ́ iwájú
Èèyàn tí ò bá lẹ́gbẹ́ láyé Àyìndé Wasiu kò le ní lọ́run
Ibi kálukú bá tò sí, ibẹ̀ ló máa dúró sí
Bó bá dijọ́ ọjọ́ kan ẹ ẹ̀ ri bí?
Christ Apostolic, congratulation 65th Anniversary mo kí gbogbo wa
Ọlọ́hun má ba ìgbà yìí jẹ́ o (Àmín o)
Ọlọ́hun má ṣe ba ìgbà yìí jẹ́ (Àmín o)
Àmín o (Àmín o)
Happy Anniversary (Àmín o)
Christ Apostolic Grammar School (Àmín o)
Ọlọ́hun má b’àgbà yìí jẹ́ fún gbogbo wa (Àmín o)
Ọlọ́hun má ṣe b’àgbà yìí jẹ́ (Àmín o)
Ọlọ́hun má ṣe b’àgbà yìí jẹ́ (Àmín o)
À á máa lékún nínú ọlá ńlá (Àmín o)
Mo kí Kábíèsí o (Àmín o)
Ọba Alápẹru (Àmín o)
Gbogbo àwọn ọmọ yín wọ́n ń dúpẹ́ (Àmín o)
Classroom blocks tẹ́ ẹ kọ́ yẹn kò ì tó (Àmín o)
Ọlọ́hun á f’agbára kún agbára (Àmín o)
Ẹ tún ṣe ju bẹ́ẹ̀ lọ (Àmín o)
Gbogbo ọmọ Christ Apostolic pátápátá (Àmín o)
Okay, Apolly grams jẹ́ n r’ọ̀wọ́ọ yín o (Àmín o)
Ansarudeen lèmi (Àmín o)
Ṣùgbọ́n a ti wá’bí rí (Àmín o)
À ti wá ka yín mọ́’lé rí (Àmín o)
Ọlọ́hun má ba ìgbà yìí jẹ́ gbogbo wa (Àmín o)
Ọlọ́hun mi o (bàbá o ṣé)
Ọlọ́hun mi o (bàbá o ṣé)
Kábíèsí Ọba Basibo Alápẹru o ní’pẹru Rẹ́mọ
Aláyélúwà mo kí i yín
Mo gba ara tiyín mo fi kí Kábíèsí Àkárìgbò àti gbogbo Ọba aládé ládé níkàlẹ̀
Ẹbìdènà a kú oríire tèní
Happy Anniversary Àyìndé Wasiu mo kí gbogbo wa
Mo dúpẹ́ Ọlọ́hun mi o (bàbá o ṣé)
Christ Apostolic Grammar School old Student Association
Àṣọdún mọ́dún á máa j’áwo àṣọdún mọ́dún
Àṣoṣùmóṣù a máa ga si
Torí mo r’ọ́wọ́ ìkẹ́ Ọlọ́hun (mo ri nínú iṣẹ́ mi)
Láti orí olórí ẹgbẹ́ Old Student Association àwọn Executive àsìkò yìí
National President Tèmítọ́pẹ́ Akíntúndé
Armstrong congratulation, mo kí ẹ Tèmítọ́pẹ́
Aláṣẹ Aerofield homes and properties
Á kú oríire t’eléyìí Àyìndé Ọmọ́gbọ́láhàn mo kí gbogbo wa
Torí mo r’ọ̀wọ́ ìkẹ́ Ọlọ́hun (mo ri nínú iṣẹ́ mi)
Èmi r’ọ́wọ́ àánú Ọlọ́hun (mo ri nínú iṣẹ́ mi)
Mo r’ọ́wọ́ ìkẹ́ Ọlọ́hun Ọba (mo ri nínú iṣẹ́ mi)
Jíjẹ mímu nírọ̀rùn (la ṣe ń dúpẹ́ f’Ọ́lọ́hun)
Àní ká lọ ká bọ̀ nípẹ̀sẹ̀ o (la ṣe ń dúpẹ́ f’Ọ́lọ́hun)
À ń lọ à ń bọ̀ nípẹ̀sẹ̀ (la ṣe ń dúpẹ́ f’Ọ́lọ́hun)
Ẹni mọ oore Ọlọ́hun o
Ìwọ to m’oore Ọlọ́hun ya tú kẹ̀kẹ́ ijó sílẹ̀ ó yá
(M’oore Ọlọ́hun, bó bá m’oore Ọlọ́hun)
(Kó tú kẹ̀kẹ́ ijó sílẹ̀ ó yá)
Ìwọ to m’oore Ọlọ́hun ya tú kẹ̀kẹ́ ijó sílẹ̀ ó yá
(M’oore Ọlọ́hun, bó bá m’oore Ọlọ́hun)
(Kó tú kẹ̀kẹ́ ijó sílẹ̀ ó yá)
Òbùró fi’ṣẹ́ tó ń ṣe sílẹ̀ (wá jó ó ń kí)
Ọkọ ìyàwó fi’ṣẹ́ tó ń ṣe sílẹ̀ (wá jó ó ń kí)
Ijọ́ o bá fẹ́ sin’mọ níyàwó (báwo lo ti a jó)
Ijọ́ o bá fẹ́ sin’mọ níyàwó (báwo lo ti a jó)
Àní ijọ́ o bá fẹ́ ṣègbéyàwó (báwo lo ti a jó)
Kíámọ́sá yá a dìde ńlẹ̀ kó o mújó ọ̀rọ̀ rè é ijó oge (bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kó o mújó oge)
Ẹ̀yin Apolo grams
Kíámọ́sá yá a dìde ńlẹ̀ kó o mújó ọ̀rọ̀ rè é ijó oge (bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kó o mújó oge)
Ó dàbọ̀ ọjà o kádẹ̀ ì mújó yẹn tó kù ó di bálẹ́ bá lẹ́
(Ó dàbọ̀ ọjà o)
Ká í mújó yẹn tó kù ó di bálẹ́ bálẹ́ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Tòkunbọ̀ Fákọ̀yà o ò gbọ́ bí mo ṣe ń sọ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Àpésìnọlà o ò gbọ́ bí mo ṣe ń sọ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ọmọ Apẹ́lógun o ò gbọ́ bí mo ṣe ń sọ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Kábíèsí Alápẹru Àyìndé mo kí Ọba (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ọba Ẹbidènà awo bàbá Ọba ló ń kí ẹ
Àyìndé Wasiu o ò gbọ́ bí mo ṣe ń sọ (ó dàbọ̀ ọjà o)
Ẹ̀yin Apolo grams okay now
Tí n bá ṣe báyìí o (àrà me dá)
Okay tí n bá tún gbẹ́sẹ̀ (àrà me dá)
Bí n ṣé báyìí o (àrà me dá)
Bí n bá tún gbẹ́sẹ̀ ṣẹ́ ( ara me dá)
Ẹti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí
Ònípélé alábàjà o
Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí o
(Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí)
(Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí)
(Ònípélé alábàjà o ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí o)
Ẹti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí
Ònípélé alábàjà o
Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí o
(Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí)
(Ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí)
(Ònípélé alábàjà o ẹ ti ṣe sọ̀rọ̀ mi sí o)
Ó dàbọ̀ ọjà o kádẹ̀ ì mújó yẹn tó kù ó di bálẹ́ bá lẹ́
(Ó dàbọ̀ ọjà o)
Ká í mújó yẹn tó kù ó di béré báyá (ó dàbọ̀ ọjà o)
Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀
Ẹ jẹ́ á kàá síwájú
Ẹ má jẹ̀ ó já
Ẹ má jẹ̀ ó já
Ẹ má jẹ̀ ó já
Ẹ má jẹ̀ ó já
Ẹ má jẹ̀ ó jábọ́’lẹ̀ o
Bí’jó bá ti yá ẹ jẹ́ á jó
Olúayé Fújì ló ń bọ́
Níṣe ni wọn ò mọ̀ Àyìndé Wasiu sọ fún wọn
(Wọ́n tún ń na, wọ́n ń k’ówó le)
Níṣe ni wọn ò mọ̀ Àyìndé Wasiu sọ fún wọn
(Wọ́n tún ń na, wọ́n ń k’ówó le)
Àwa ṣá la nílẹ̀ yìí o
O ò gbọ́ b’ọ́ba Fújì ṣe ń bọ́
Mo ní àwa ṣá la nilẹ̀ yìí o
Gbangbadẹkùn o (kedere bẹ̀ẹ́wò)
(Gbangbadẹkùn o kedere bẹ̀ẹ́wò)
Gbangbadẹkùn o (kedere bẹ̀ẹ́wò)
(Gbangbadẹkùn o kedere bẹ̀ẹ́wò)
Ọ̀rọ̀ yìí wá di Saliu Butushi o
(Ẹṣin burúkú ijó lẹ́sẹ̀ eré ló ń lọ)
Ó di Saliu Butushi o
(Ẹṣin burúkú ijó lẹ́sẹ̀ eré ló ń lọ)
Mo ní ó di Saliu Butushi o
(Ẹṣin burúkú ijó lẹ́sẹ̀ eré ló ń lọ)
Apolly grams máa wò mí o (máa wò mí)
Mo ní máa wò mí o (máa wò mí)
Máa wò mí (máa wò mí)
Máa wò mí (máa wò mí)
Máa wò mí (máa wò mí)
Máa wò mí (máa wò mí)
Ìgbà tó ò dé ìlú (lo ò m’ẹ̀yọ̀)
Ibí gangan l’original
O ò dé’lùú (o ò mẹ̀yọ̀)
O ò dé’lùú (o ò mẹ̀yọ̀)
O ò dé’lùú (o ò mẹ̀yọ̀)
Ọ̀rọ̀ yìí wá di Saliu Butushi o
(Ẹṣin burúkú ijó lẹ́sẹ̀ eré ló ń lọ)
Ó di Saliu Butushi o
(Ẹṣin burúkú ijó lẹ́sẹ̀ eré ló ń lọ)
Mo ló di Saliu Butushi o
(Ẹṣin burúkú ijó lẹ́sẹ̀ eré ló ń lọ)
Written by: Olasunkanmi Ayinde Marshal

