album cover
Impact Pt. 2
album cover
00:00
06:00
07:35
07:50
16:15
00:00
17:09
Past 7 Days
Impact Pt. 2 was discovered most frequently at around 7 minutes and 35 seconds into the song during the past week

Music Video

Music Video

Lyrics

Òdú ni wá Saheed ah
Òdú mà ni wá o
A ì í ṣe àìmọ̀ fún olóko
Ọmọdé mọ̀ wá àwọn àgbàgbà mọ̀ wá
Ọ̀gbọ́ǹtariìgì nínú olórin ṣá ni èmi
Ògúnnágbọ̀ǹgbò nínú eré ìtàgé ni mí
Òdú ni wá Saheed ah
Òdú mà ni wá o
A ì í ṣe àìmọ̀ fún olóko
(Ọmọdé mọ̀ wá àwọn àgbàgbà mọ̀ wá)
(Ọ̀gbọ́ǹtariìgì nínú olórin ṣá ni èmi)
(Ògúnnágbọ̀ǹgbò nínú eré ìtàgé ni mí)
Kí wọ́n tó mọ̀ wá o ọmọ kò easy o
A ti ṣiṣẹ́ gan kí Ọlọ́hun tó sọ wá di ògo
Ògbóǹtarìgì nínú olórin ṣá ni èmi
Ògúnnágbọ̀ǹgbò nínú eré ìtàgé ni mí
Ẹ ò fi iṣẹ́ ṣeré Saheed ah
Àní kí wọ́n tó mọ̀ wá o ọmọ kò easy o
(A ti ṣiṣẹ́ gan kí Ọlọ́hun tó sọ wá di ògo)
(Ògbóǹtarìgì nínú olórin ṣá ni èmi)
(Ògúnnágbọ̀ǹgbò nínú eré ìtàgé ni mí)
Torí égbè ńlá ni èmi
Égbè ńlá baba Suliatu
(You're fully loaded)
(O ò mọ̀ pé kò bana)
(Kín ni wọ́n fẹ́ fi kun)
(Kín ni wọ́n fẹ́ fi kun, kò bragado)
(Ó kira gan nínú olórin kò tẹtẹrẹ)
Àní égbè ńlá lèmí
Égbè ńlá baba Suliatu
(You're fully loaded)
(O ò mọ̀ pé kò bana)
(Kín ni wọ́n fẹ́ fi kun)
(Kín ni wọ́n fẹ́ fi kun, kò bragado)
(Ó kira gan nínú olórin kò tẹtẹrẹ)
Ṣèbí o mọ bí wọ́n ṣe máa ń tẹ̀ka
Tẹ̀ka báyìí
Tẹ̀ ẹ́ sí Google ìwọ gan á ri pé ó ṣì ń lọ
Yahoo ẹ̀ wò, á gbe jáde global ni
To bá ń tweet ayé ń yapa
Tí wọ́n ń tẹ̀le
Kò wá pin s’órí ilẹ̀
To fi dé orí i baddoo ni
Bí èèyàn ò rí wa ri o
Á ti rí photo rẹpẹtẹ
Ṣèbí o mọ bí wọ́n ṣe máa ń tẹ̀ka
Tẹ̀ka báyìí
Tẹ̀ ẹ́ sí Google ìwọ gan á ri pé ó ṣì ń lọ
Yahoo ẹ̀ wò, á gbe jáde global ni
To bá ń tweet ayé ń yapa
Tí wọ́n ń tẹ̀le
Kò wá pin s’órí ilẹ̀
To fi dé orí i baddoo ni
Bí èèyàn ò rí wa ri o
Á ti rí photo rẹpẹtẹ
Saridon P Saheed mi
Saridon P Ọlọ́hun-ún wà
(Èṣú mọ̀, ẹ ti mọ irú èèyàn tí a jẹ́)
(Ẹ kàn lè má gbà)
(Ẹ jẹ́ lọ wọ́n omi sí iṣan)
(Gbogbo ayé mọ Nike mi)
(Ó le ju Puma nínú olórin o tẹnu kọ́)
Gbogbo ayé mọ Nike mi
Láti ayé ìgba scores
Saridon P Ọlọ́hun-ún wà
(Èṣú mọ̀, ẹ ti mọ irú èèyàn tí a jẹ́)
(Ẹ kàn lè má gbà)
(Ẹ jẹ́ lọ wọ́n omi sí iṣan)
(Gbogbo ayé mọ Nike mi)
(Ó le ju Puma nínú olórin o tẹnu kọ́)
Bó o bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀
Wọ́n á ní ọmọ sọ ìmíì si
Wọ́n á ní ayé ò to ẹjọ́
Ọmọ ṣókí ni lédè kan
Gbogbo atótónu mo ṣe igbá
Mo tún ṣe àwo
Wọ́n á ní a ti gbọ́
Wọ́n á ní ó da ṣè’míì si
Yé tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ kan
Torí to bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀
(Wọ́n á ní ọmọ sọ ìmíì sì)
(Wọ́n á ní ayé ò to ẹjọ́)
(Ọmọ ṣókí ni lédè kan)
(Gbogbo atótónu mo ṣe igbá)
(Mo tún ṣe àwo)
(Wọ́n á ní a ti gbọ́)
(Wọ́n á ní ó da ṣè’míì sì)
Wọ́n á ní ó dà bíi pé ẹnu yín ń ṣièrè
(Ẹ tètè lọ ran pa)
(Mo rò pé ẹ jẹ ata)
(Ẹnu yín ń ta yín jù ni)
(Ṣé ẹ máa ń jẹ ìlá ni ẹnu yín ṣe ń yọ̀ ni)
(Tí wọ́n ò bá pè èèyàn sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ o)
(Tí o na ẹnu)
Wọ́n á ní ó dà bíi pé ẹnu yín ń ṣièrè
(Ẹ tètè lọ ran pa)
(Mo rò pé ẹ jẹ ata)
(Ẹnu yín ń ta yín jù ni)
(Ṣé ẹ máa ń jẹ ìlá ni ẹnu yín ṣe ń yọ̀ ni)
(Tí wọ́n ò bá pè èèyàn sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ o)
(Tí o na ẹnu)
Tí wọ́n bá ní ọmọ má sun ìgbá jẹ wàá wúkọ́
(Ìgbá jíjẹ kọ́ ni wọ́n ń wí la etí’lẹ̀ o)
(Ìyà jíjẹ ni wọ́n mà ń sọ o lo ọpọlọ)
Tí wọ́n bá ní ọmọ má sun ìgbá jẹ wàá wúkọ́
Àṣà ni
Tí wọ́n bá ní ọmọ má sun ìgbá jẹ wàá wúkọ́
(Ìgbá jíjẹ kọ́ ni wọ́n ń wí la etí’lẹ̀ o)
(Ìyà jíjẹ ni wọ́n mà ń sọ o lo ọpọlọ)
BÍ wọ́n fẹ́ kí n kun ilẹ̀ lọ́dà o
Wọ́n á ní ẹnú gbẹ
BÍ wọ́n fẹ́ kí n kun ilẹ̀ lọ́dà
(Wọ́n á ní ẹnú gbẹ, bàbá kí ló ń bọ̀)
(Tí n bá fẹ́ ya owó, wọ́n á ní omi la fẹ́ fà o)
(Tìgòtìgò là ń rọ ọtí olóyìnbó)
(Ṣùgbọ́n tí ẹlẹ́mu bá ní òun ò ta àgbè mọ́)
(Ẹ fọ kẹ gbe mu)
(Ṣ’ó ju owó lọ màá sanwó)
Àwọn Padi mi níbìkan
Wọ́n fẹ́ kí n kun’lẹ̀ lọ́dà
Wọ́n á ní ẹnú gbẹ
(Bàbá kí ló ń bọ̀)
(Tí n bá fẹ́ ya owó, wọ́n á ní omi la fẹ́ fà o)
(Tìgòtìgò là ń rọ ọtí olóyìnbó)
(Ṣùgbọ́n tí ẹlẹ́mu bá ní òun ò ta àgbè mọ́)
(Ẹ fọ kẹ gbe mu)
(Ṣ’ó ju owó lọ màá sanwó)
Àwọn olóshó àdúgbò mi
Àwọn àṣànà mi
Àwọn olóshó tí ará bá tutù
Wọ́n shó mi tí n bá ti tọ̀ ọ́
Àwọn àṣànà gán ma mú mi mọ́lẹ̀ ni
Wọ́n á ṣa lé mi bí ẹní ra motor ni
Wọ́n á ní saridon papa
Ṣé ìwọ kọ́ ẹrù tó lutí
Àwọn olóshó àdúgbò mi
Àwọn àṣànà mi
Àwọn olóshó tí ará bá tutù
Wọ́n shó mi tí n bá ti tọ̀ ọ́
Àwọn àṣànà gán ma mú mi mọ́lẹ̀ ni
Wọ́n á ṣa lé mi bí ẹní ra motor ni
Wọ́n á ní saridon papa
Ṣé ìwọ kọ́ ẹrù tó lutí
Wọ́n ti mọ̀ pé bọ̀bọ́ ò kí n ṣakọ
Àbàshà ni ò fẹ́
Tèmí ni pé ṣe normal
Kí èmi gan ra hummer fún ẹ
Èmi ò fẹ́ mọ̀ bóyá o ti ṣe sí ẹnìkan
Mi ò jísòró bóyá o dé ilé e Padi mi rí
Wọ́n ti mọ̀ mí jù o
Wọ́n ti mọ̀ pé bọ̀bọ́ ò kí n ṣakọ
Àbàshà ni ò fẹ́
Tèmí ni pé ṣe normal
Kí èmi gan ra hummer fún ẹ
Èmi ò fẹ́ mọ̀ bóyá o ti ṣe sí ẹnìkan
Mi ò jísòró bóyá o dé ilé e Padi mi rí
Ṣé ẹ tún wá rí tí n bá fẹ́ jẹ jìgá
(Mo lè fẹ́ ọmọ ghetto)
Tí n bá fẹ́ jayé jù
(Mo lè fẹ́ ọmọ Lògbà lògbà)
Tí n bá fẹ́ mi ìgboro
(Mo lè fẹ́ Aganga)
BÍ n fẹ́ ṣe papapa
(Mo lè fẹ́ Amina papapa)
(Ǹ bá dẹ̀ tún fẹ́ Ọmọ́tárá Johnson o)
(Ẹ̀rùn Déwùmí ìbẹ̀rù ló ń bà mí)
(Ǹ bá fẹ́ Kòfó Tinubú á yọ mi lẹ́nu)
(Ǹ bá fẹ́ Àríkẹ́ o ó ta lẹ́nu jù ní tèmi)
Tí n bá fẹ́ jẹ jìgá
(Mo lè fẹ́ ọmọ ghetto)
Tí n bá fẹ́ jayé jù
(Mo lè fẹ́ ọmọ Lògbà lògbà)
Tí n bá fẹ́ mi ìgboro
(Mo lè fẹ́ Aganga)
BÍ n fẹ́ ṣe papapa
(Mo lè fẹ́ Amina papapa)
(Ǹ bá dẹ̀ tún fẹ́ Ọmọ́tárá Johnson o)
(Ẹ̀rùn Déwùmí ìbẹ̀rù ló ń bà mí)
(Ǹ bá fẹ́ Kòfó Tinubú á yọ mi lẹ́nu)
(Ǹ bá fẹ́ Àríkẹ́ o ó ta lẹ́nu jù ní tèmi)
Ìgboro ni Báráká
(Iṣan ni Ikeduba)
(Ṣé ẹ rí shingbaka ọmọ Ọdúnladé pọ̀ gan)
(Bàbá Ìjẹ̀sà ò fi gbogbo ara gbádùn o)
(Gọ̀lúgọ̀ ò gọ̀ ó ṣe bí ẹní gọ̀ ni)
(Ta ló ní agídí tó tó ti Lala gan)
(Jẹ̀lílì gán só ó gba recognition o)
(Ohun tí èèyàn bá mọ̀ọ́ ṣe láyé o tẹra mọ)
Ìgboro ni Báráká
(Iṣan ni Ikeduba)
(Ṣé ẹ rí shingbaka ọmọ Ọdúnladé pọ̀ gan)
(Bàbá Ìjẹ̀sà ò fi gbogbo ara gbádùn o)
(Gọ̀lúgọ̀ ò gọ̀ ó ṣe bí ẹní gọ̀ ni)
(Ta ló ní agídí tó tó ti Lala gan)
(Jẹ̀lílì gán só ó gba recognition o)
(Ohun tí èèyàn bá mọ̀ọ́ ṣe láyé o tẹra mọ)
Ẹ ẹ̀ rí àfọ̀njá Láníyì mi
Ẹ ẹ̀ rí Sányẹ̀rì tí wọ́n ń sọ nígboro
(Tó mu wèrè yó nínú ìkọjáàyè)
(Ẹ ẹ̀ rí Sányẹ̀rì nínú ọ̀pá kan)
(Tó fi mílìkì méjì mu Maltina kan)
(Ẹ ẹ̀ mọ sányẹ̀rì tí wọ́n sọ pé ó kọlà tó párí)
Ẹ ẹ̀ rí àfọ̀njá Láníyì mi
Ẹ ẹ̀ rí Sányẹ̀rì tí wọ́n ń sọ nígboro
(Tó mu wèrè yó nínú ìkọjáàyè)
(Ẹ ẹ̀ rí Sányẹ̀rì nínú ọ̀pá kan)
(Tó fi mílìkì méjì mu Maltina kan)
(Ẹ ẹ̀ mọ sányẹ̀rì tí wọ́n sọ pé ó kọlà tó párí)
Òhun ni wọ́n fi ń dá’ṣà yẹn
Ni wọ́n fi ń dá’ṣà pé Chinko ni phone o
(China ni ìlú ẹ̀)
(Ọ̀kọlà ní America tó fẹ́ máa ṣe ìṣe akátá)
(Ta ni ò ní mọ̀ wí pé Africana ni)
(Ẹ ẹ̀ mọ sányẹ̀rì tí wọ́n sọ pé ó kọlà tó párí)
Òhun ni wọ́n fi ń dá’ṣà yẹn
Ni wọ́n fi ń dá’ṣà pé Chinko ni phone o
(China ni ìlú ẹ̀)
(Ọ̀kọlà ní America tó fẹ́ máa ṣe ìṣe akátá)
(Ta ni ò ní mọ̀ wí pé Africana ni)
(Ẹ ẹ̀ mọ sányẹ̀rì tí wọ́n sọ pé ó kọlà tó párí)
Ká tó di ẹni tí ayé ń fẹ́ o
Ojú ti rí tó
Ká tó di ẹni tí ayé ń fẹ́ o
Ojú ti rí tó
Àwọn tí àwa ń ro ọkà fún jẹ
Ìka tó bọ́ wọn ni wọ́n padà gé jẹ
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run á padà mú wọn
A di ẹni tí ayé ń fẹ́ o
(Ojú ti rí tó)
(Ká tó di ẹni tí ayé ń fẹ́ o)
(Ojú ti rí tó)
(Àwọn tí àwa ń ro ọkà fún jẹ)
(Ìka tó bọ́ wọn ni wọ́n padà gé jẹ)
(Ṣùgbọ́n Ọlọ́run á padà mú wọn)
Ká tó di ẹni tí ayé ń fẹ́ o
Ojú ti rí tó
Ká tó di ẹni tí ayé ń fẹ́ o
Ojú ti rí tó
Àwọn tí àwa ń ro ọkà fún jẹ
Ìka tó bọ́ wọn ni wọ́n padà gé jẹ
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run á padà mú wọn
A di ẹni tí ayé ń fẹ́ o
(Ojú ti rí tó)
(Ká tó di ẹni tí ayé ń fẹ́ o)
(Ojú ti rí tó)
(Àwọn tí àwa ń ro ọkà fún jẹ)
(Ìka tó bọ́ wọn ni wọ́n padà gé jẹ)
(Ṣùgbọ́n Ọlọ́run á padà mú wọn)
Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn
Ẹ gbọ́ tí Ọlọ́hun bá sọ pé
Ó ṣì tún kù ńkọ́?
Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Àní tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn
Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó ṣì tún kù ńkọ́ o
Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Ṣé ẹ rí ẹni ayé ti dí lọ́wọ́ pé kò lè là
Ẹni ayé ti dí lọ́wọ́ o pé kò lè là
Tí Ọlọ́hun bá lọ gbé búrùjí dìde ńkọ́ o
Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Ẹ̀gẹ́ bàbá Abida Àlàó ṣènìyàn
Èèyan olórí Sir kay Kamo ṣènìyàn
Èèyan Táńtálá náà ni èèyàn wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Etu Babátúndé ó mà wá ṣènìyàn
Ọkọ Ọlábísí ó mà wá ṣènìyàn
Bàbá Fathia Abia èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Luku àjàó ó dẹ̀ tún ṣènìyàn
Èèyàn kọ́ládé ASPOR gán ṣènìyàn
Èèyan koko below Lati ṣènìyàn
Èèyan Awe Microwaheed èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Mọ́gàjí Babátúndé Dégòkè ṣènìyàn
Ọkọ Táyélolú wọ́n mà wá ṣènìyàn
Olóòkúta Mọ́gàjí èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Chris Àgbẹ̀dẹ ló dẹ̀ tún ṣènìyàn
Ọkọ kẹ́hìndé eléjìrẹ́ èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Ọkọ Bọ́láńlé ló mà tún ṣènìyàn
Oradis Àdísá ọmọ Elédùwe
Òun ni ọ̀gbágbá agbọ́tẹ̀wọlẹ̀ níwọ̀nba èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Torí ẹni ayé ti dí lọ́wọ́ pé kò lè là
Ẹni ayé ti dí lọ́wọ́ o pé kò lè là
Tí Ọlọ́hun bá lọ gbé búrùjí ẹ̀ dé ńkọ́ o
Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa
(Tí ẹ̀dá bá sọ pé ó mà tán fún ènìyàn)
(Tí Ọlọ́hun bá sọ pé ó sì tún kù ńkọ́ o)
(Ibo lọ̀tá ó fojú sí ẹ̀yin èèyan wa)
Mr Music, Mr Music
(Na you biko Saridon P)
(You're just too much Saridon P)
Mr Music, Mr Music
(Na you biko Saridon P)
(You're just too much Saridon P)
King of Music, king of music
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonders Saridon P)
King of Music, king of music
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonders Saridon P)
Gbogbo ilé tó fẹ́ dàrú
To fi orin túnṣe padà ńkọ́, Yes
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonders Saridon P)
Gbogbo ilé tó fẹ́ dàrú
To fi orin túnṣe padà ńkọ́, ah
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonder Saridon P)
Gbogbo ẹni tí ò ní ìrètí
Tó di ẹni tó wà hopeful ńkọ́
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonders Saridon P)
Gbogbo ẹni tí ò ní ìrètí
Tó di ẹni tó wà hopeful ńkọ́
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonders Saridon P)
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó o gbìn sínú
Gbogbo ẹni tí ọkàn wọn dọ̀tí ńkọ́
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonders Saridon P)
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó o gbìn sínú
Gbogbo ẹni tí ọkàn wọn dọ̀tí ńkọ́
(Kò le è yé wọn o Saridon P)
(You've done wonders Saridon P)
Mr Music, Mr Music
(Na you biko Saridon P)
(You're just too much Saridon P)
Written by: Okunola Saheed
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...