类似歌曲
制作
出演艺人
Brymo
表演者
作曲和作词
Olawale Olofo'ro
词曲作者
制作和工程
Mikkyme Joses
制作人
歌词
[Verse 1]
Ifẹ mi dariji mi
Ọmọde ni ṣe mi
Afarawe o ṣe temi
Ka daduro ni mo wa ri
Mo ti sọ tẹlẹtẹlẹ ri
Igboro o ma rẹrin-in ri
Ijakadi lo mu niṣẹ
Karohunwi o bọpọ ṣiṣẹ
[PreChorus]
Bi n ba fa a wọn a lo le
Bi n ba tulẹ wọn a lo rọ
Bi n duro wọn ma mere
Bi n ba sa wọn a ni mo kere
[Chorus]
Abalọ ababọ
Bo wu wọn k'ọn para wọn o
Ohun a ni la n nani
Temi ni temi
[Verse 2]
Awẹlẹwa foriji mi
Mo lakaka ki n to debi
Rirọ mẹdẹ o ṣe temi
Nibi lile la n bọkunrin
Ifẹ rẹ ṣa lo n duro ti mi
O dudu, o funfun, o pupa
Ifẹ rẹ ṣa lo n munu tu mi
Ninu ẹrun atojọ, atailera
[PreChorus]
Bi n ba fa a wọn a lo le
Bi n ba tulẹ wọn a lo rọ
Bi n duro wọn ma mere
Bi n ba sa wọn a ni mo kere
[Chorus]
Abalọ ababọ
Bo wu wọn k'ọn para wọn o
Ohun a ni la n nani
Temi ni temi
[Outro]
Abalọ ababọ
Temi lo jẹ lalẹ eni oh
Gbogbo igba ti o ba lọ
Mo mọ pe o pada wa
Written by: Olawale Olofo'ro