歌词
Eni a wi fun oba jio gbo
Baale ile ti o mo rare l'agba
To n se langbalangba oh, l'oja oba
To n kigbe eyin mi nu oh, afi kin sha lo ja
Omo to to bi l'omo oun lo ba wo yaya
E fi sile oh, o fe te oh, ori okere koko lawo
Edaaku e ma ba wi oh, igbeyin ni do loku ada oh
Shaki to n se bi ora, pelepele ko rora oh
Aifarabale agba a ma je agba fara gbe'gba
Igboron ta n wi oh, o san ju ebo ruru lo
Owe agba
Eni a wi fun oba je o gbo
Oro agba
Alagidi ki palemo atu bo tan oh
Owe agba
Oun omo je, ama se iku p'omo
Aboro la n so f'omoluabi
To ba de be a di odindi
Iya ile le yi oh, eweso
Anu re lo n se mi oh, lo je mba o damoran
Bara ile eni ba n je ekute oni dodo
Afi ka kilo fun, ka ba soro ododo
Omo baba n fe oh, ni baba n ba wi oh
Iyi to ko ibawi oh, to n wa arunki, ah
N fi sile oh, o fe te oh, ori okere koko lawo
Edaaku e ma ba wi oh, igbeyin ni do loku ada oh
Shaki to n se bi ora, pelepele ko rora
Agba tio farabale ama fara gbe'gba
Igboron ta n wi oh, o san ju ebo ruru lo
Owe agba
Eni a wi fun oba je o gbo oh
Oro agba
Alagidi ki palemo atu bo tan oh
Owe agba
Oun omo je, ama se iku p'omo
Igboron ta n wi oh, o san ju ebo ruru lo
Owe agba
Oni a wi fun oba je o gbo
Oro agba
Alagidi ki palemo atu bo tan oh
Owe agba
Oun omo je, ama se iku p'omo
Oun t'oju arugbo ri to fi ko wonu
B'omode ba ri, a de fo loju
Iku diasi to loun ti ba iku mule ri
Ko lo bere lowo iku, oun to ri to fi pa lori
B'omo ba laso bi agba
Ko le lakisa bi agba
Oromo adiye larin asha oh
To fi ta iku laya
Igboron ta n wi oh, o san ju ebo ruru lo
Owe agba
Oni a wi fun oba je o gbo
Oro agba
Alagidi ki palemo atu bo tan oh
Owe agba
Oun omo je, ama se iku p'omo
Igboron ta n wi oh, o san ju ebo ruru lo
Owe agba
Oni a wi fun oba je o gbo
Oro agba
Alagidi ki palemo atu bo tan oh
Owe agba
Oun omo je, ama se iku p'omo
Written by: Kehinde Daniel Hassan