積分
演出藝人
Tope Alabi
演出者
詞曲
Patricia Temitope Alabi
詞曲創作
歌詞
[Verse 1]
Alagbawi mi onigbọwọ to yọ mi loko iya o
Alagbawi mi onigbọwọ to yọ mi l'okun
Mo dupẹ, o ṣe, to san igbese mi
Mo dupẹ, o ṣe, to san gbese mi
Iwọ lo yọ mi loko iya ti mo kori mi bọ
Ani iwọ lo yọ mi loko oṣi ti mo kẹsẹ mi bọ
O ṣe, mo dupẹ, to san igbese mi
O ṣe o, mo dupẹ, to san igbese mi
[Chorus]
Alagba wi mi (Alagba wi mi)
Onigbọwọ ẹda (Onigbọwọ mi)
O ṣeun, to san gbese mi (O ṣe o) To san igbese mi
Ọpẹ ni mo wa du nitemi (Alagbawi mi, onigbọwọ mi o ṣeun to san igbese mi)
[Verse 2]
Orun yọ tori mi
Mo d'ominira a tu mi silẹ
Emi ajigbese ọjọsi
Agbelebu tu mi silẹ po
Eleso ajẹku, o ti kogbawọle
Eleso ajẹku, o ti ko igba wọle (O kogbawọle po)
[Chorus]
Alagbawi mi (Bẹẹ ni bẹẹ ni) Onigbọwọ mi (Ọpẹlọpẹ olugbala mi)
O ṣeun to san igbese mi (O ṣe to san obese aye mi)
Alagbawi mi, onigbọwọ mi
O ṣeun to san gbese mi
[Verse 3]
Iyan ki ṣẹgbẹ iṣu laye
Ma fọtọ lori iwe panduku
Ibi iṣubu yatọ sibi idide
Ọgba edeni lakoba ti wa
A tun ipin ẹda yan lati ibi agbari
A tori aye ṣe ni calvary
Agbelebu ibi ifẹṣẹ jin
A ka iboju kuro aṣọ ipọnju faya
Alapagbe oniyangi oju ẹ mọ
O dẹni ifibu porogodo
Alapagbe ti kogbawọle
[Chorus]
Alagbawi mi (O ṣe Olodumare)
Onigbọwọ mi (Alagbawi onigbọwọ mi) o
O ṣeun, to san igbese mi (O ṣe ooooo)
Alagbawi wi mi (Alagbawi mi)
Onigbọwọ mi (Onigbọwọ ẹda)
O ṣeun, to san igbese mi
[Verse 4]
Akọsilẹ gbese ti parẹ
Kosi iwulo afidogo mọ
Ajigbese bọ logun asingba
Ẹjẹ rajigbese atẹnidogo
Ẹni ti n ya dẹni ti n fọnka
Ẹku ibanuje wa di ẹrin
Ajigbese atadogo a ti bọ
Igi ti da okun ti ja
Awa ti yọ
Ẹni to n wogi oro oun lo ri iye
Ominira de (Ominira ti de)
[Chorus]
Alagbawi mi (Atadogo)
Onigbọwọ mi (Atoni gbese)
O ṣeun, to san gbese mi (Atajigbese awa mẹtẹẹta)
Alagbawi mi (La ba bọ loko iya o)
Onigbọwọ mi (Laba bọ loko ẹru)
O ṣeun, to san gbese mi (Ọpẹlọpẹ onigbọwọ alagbawi ẹda o)
[Verse 5]
Ọpẹ onifẹẹ alailẹgbẹ
Ogo folugbala to jokoo nitẹ aanu
Ọpẹ alagbawi igbọwọ ẹda o
O waye wa fi iku agbekọrun mi tẹlẹ jona
O kọ mi nila iya t'onikọla aye o le kọ o
Ẹmi mimọ wa di ogun ibi si iye fun emi
[Verse 6]
Mo d'ominira ah ah, mo dọmọ
Mo d'ominira eh eh, mo yege
Baba mi lo laye at'ọrun, mo d'ominira
Mo d'ominira eh eh, mo yege
Mo d'ominira ah ah, mo dọmọ (Mo di ọmọ lat'oni lọ)
Mo d'ominira eh eh, mo yege (ṣa r'ẹni to n sọbẹ pẹlu emi)
Bẹẹni ọmọ ni mi (Mo d'ominira ah ah, mo dọmọ)
Ko si gbese lọrun mi ẹjẹ lo san gbogbo rẹ (Mo d'ominira eh eh, mo yege)
[Verse 7]
Jesu san gbese mi tan, mo bọ lọwọ aninilara
Alagbawi san tan mo dẹni apọnle mo dọmọ, mo dọmọ, mo d'ominira, oh oh oh oh
Mo yege mo jogun ayeraye (Mo jogun ayeraye iye ni temi)
Mo dọmọ, mo dọmọ, mo d'ominira oh oh oh oh
Mo yege, mo jogun ayeraye
[Verse 8]
Mo di ọmọ
Mo d'ominira ah ah, mo dọmọ (Mo ti d'ominira, a tu mi silẹ mo yege o)
Mo d'ominira eh eh, moyege (Alagbawi lo ṣaṣepe Iṣẹ aye mi)
Mo d'ominira ah ah, mo d'ọmọ (Onigbọwọ oun lo ṣaṣepe iṣẹ aye mi o)
Mo d'ominira eh eh, mo yege (Ko si iwulo afidogo mọ o)
Written by: Patricia Temitope Alabi

