積分

演出藝人
Sola Allyson
Sola Allyson
演出者
詞曲
Sola Allyson
Sola Allyson
作曲
Wole Adesanya
Wole Adesanya
作曲
製作與工程團隊
Wole Adesanya
Wole Adesanya
製作人

歌詞

[Chorus]
Ṣèbí mo dé'bí láìsẹ́nìkan t'ó dì mí l'ọ́wọ́ mú
Ṣèbí mo dé'bí láìsẹ́nìkan t'ó dì mí l'ọ́wọ́ mú
Àwọn t'ó yẹ k'ọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú wọ́n ọn pà mí tì
Òye ìrìn mi ò yé wọn
Ìrìn mo níláti rìn mo rìn
Ìrírí tí mo ní láti ní mo ní
Ìgbà ìrànwọ́ dé o
Ọ̀pọ̀ yí mi ká wọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú

[Verse 1]
Wọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú wọ́n p'agbo yí mi ká
Wọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú wọ́n ṣúùgbá à mi
Wọ́n l'óye ìrìn mi wọ́n gbé mi l'ọ́wọ́ ró
[Verse 2]
A mú mi dé'bí tí ò s'ẹ́nìkan t'ó dì mí l'ọ́wọ́ mú
A mú mi dé'bí tí ò s'ẹ́nìkan t'ó dì mí l'ọ́wọ́ mú
Àwọn t'ó yẹ k'ọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú
Wọ́n yìn mí nù òye ìrìn mi ò yé wọn
Ìrìn mo níláti rìn mo rìn
Ìrírí tí mo ní láti ní mo ní
Ìgbà ìrànwọ́ rèé o
Ọ̀pọ̀ yí mi ká wọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú
[Verse 3]
B'óo bá ń r'ìrìn àjò, b'óo bá ń r'ìrìn àjò láìsẹ́nìkan t'ó dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
B'óo bá ń r'ìrìn àjò láìsẹ́nìkan t'ó dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
Àwọn t'ó yẹ k'ọ́n dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
Ìṣẹ̀dá ń kó wọn pọ̀ ó ń kó wọn jọ
Ìrìn t'ó níláti rìn wa rìn
Ìrírí tí o ní láti ní wàá ní
Ìgbà ìrànwọ́ á dé o
Ọ̀pọ̀ á yí ọ ká wọ́n á dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
[Verse 4]
B'óo bá ń r'ìrìn àjò, b'óo bá ń r'ìrìn àjò láìsẹ́nìkan t'ó dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
B'óo bá ń r'ìrìn àjò, b'óo bá ń r'ìrìn àjò láìsẹ́nìkan t'ó dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
Àwọn t'ó yẹ k'ọ́n dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
Ìṣẹ̀dá ń kó wọn pọ̀ ó ń kó wọn jọ
Ìrìn t'ó níláti rìn wa rìn
Ìrírí tí o ní láti ní wàá ní
Ìgbà ìrànwọ́ á dé o
Ọ̀pọ̀ á yí ọ ká wọ́n á dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
[Verse 5]
Wọ́n á dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú wọ́n á p'agbo yí ọ ká
Wọ́n á dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú wọ́n á ṣúùgbá à rẹ
Wọ́n á dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú wọ́n á gbé ọ l'ọ́wọ́ ró
[Chorus]
A mú emi dé'bí
A mú mi dé'bí tí ò s'ẹ́nìkan t'ó dì mí l'ọ́wọ́ mú
A mú mi dé'bí tí ò s'ẹ́nìkan t'ó dì mí l'ọ́wọ́ mú
Àwọn t'ó yẹ k'ọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú wọ́n yìn mí nù
Òye ìrìn mi ò yé wọn
Ìrìn mo níláti rìn mo rìn
Ìrírí tí mo ní láti ní mo ní
Ìgbà ìrànwọ́ rèé o
Ọ̀pọ̀ yí mi ká wọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú
[Outro]
Ìgbà ìrànwọ́ rèé o
Ọ̀pọ̀ yí mi ká wọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mú
Ìgbà ìrànwọ́ á wá o
Ọ̀pọ̀ á yí ọ ká wọ́n á dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
Ìgbà ìrànwọ́ á wá o
Ọ̀pọ̀ á yí ọ ká wọ́n á dì ọ́ l'ọ́wọ́ mú
Ìgbà ìrànwọ́ dé o
Ọ̀pọ̀ yí mi ká wọ́n dì mí l'ọ́wọ́ mu
Written by: Sola Allyson, Wole Adesanya
instagramSharePathic_arrow_out

Loading...