Music Video

Music Video

Credits

PERFORMING ARTISTS
K1 De Ultimate
K1 De Ultimate
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Teni
Teni
Composer
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
Composer

Lyrics

Ọmọ Naija
Kí ní ṣe tá ò fa ara wa mọ́’ra
(Ọmọ Naija)
(Ọmọ Naija)
(Kí ní ṣe tá ò fa ara wa mọ́’ra)
Àwọn ọmọ Naija
Kí ní ṣe tá ò fa ara wa mọ́’ra
(Ọmọ Naija)
Ọ̀rọ̀ mà ré
(Ọmọ Naija)
(Kí ní ṣe tá ò fa ara wa mọ́’ra)
Mo tún dé bí mo ṣe ń dé
Ẹni a wí dé aláyìndé o
Ọmọ́gbọ́láhàn arábámbí
Ọ̀rọ́ wà nílẹ̀ tí a fẹ́ bá ara wa sọ
Bí ojú bá balẹ̀ á rí’mú
Ọmọ́gbọ́láhàn mi arábámbí mi o
Ká ṣe làákàyè dáadáa
Ayé wá di rúdurùdu
Ayé ò rójú mọ́
Ẹ̀rù wá ń bà wá o
Tá a jẹ́ Nigeria ni
Kín-ni ihun tó wá ń ṣe wá
Tí ò ṣẹlẹ̀ ní ibì kan rí
Ọ̀kan ṣá ni ilẹ̀ ayé jẹ́
Ayé ò pé méjì o
Ẹ̀yin ará mi
Bí wọ́n ti ṣe ń ṣe ní Nigeria
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ní America
Ní wọ́n ń ṣe ní ibikíbi
Láàrin funfun àti dúdú
Ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀
Níṣe ni oníkálukú gbe sí abẹ́ aṣọ ni
Ní ìlú America
Ẹ̀yìn tí wọ́n ṣe election tán o
Èdèàyedè láàrin àwọn òṣèlú
Ló dá wàhálà sílẹ̀ ní parliament l’America
Ẹ̀yin ará mi
Ó ya gbogbo ayé lẹ́nu
Pé ìlú America ó ti jẹ́ o
Ọmọ Naija
Kí ní ṣe tá ò fa ara wa mọ́’ra
(Ọmọ Naija)
(Ọmọ Naija)
(Kí ní ṣe tá ò fa ara wa mọ́’ra)
Hausa ti Ibo pẹ̀lú Yorùbá wá
Kín ní ṣe tí à ń ṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà
Tí a sì ń wá ìṣubú ara wa
Ní ibi tó yẹ ká ti pa ọwọ́ pọ̀ ká di ìkan
A wá ń gbe ní oríṣíríṣi
Ṣùgbọ́n ti àwa Yorùbá ló kàn mí jù
Gẹ́gẹ́ bí i ipò mi Máyégún
Àsìkó ti tó ká pa ọwọ́ pọ̀
Ká di ìkan ṣoṣo
Tí a ò bá gbàgbé o
Kó tó di pé Nigeria gba òmìnira
Ọba òyìnbó ti wá sí Nigeria rí o
Queen Elizabeth II ní January 1956
Bó Ṣẹ́ dé ilẹ̀ ẹ Ibo ló dé ilẹ̀ Hausa
Ó yà sún oorun ọjọ́ kan ní Ìjẹ̀bú òde
Lọ́dọ̀ Chief Timothy Adéọlá
Ọ̀gbẹ́ni Ọjà mi Òdútọ́lá
Tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ bàbá Ọba òyìnbó
History ló sọ fún mi Àyìndé o
Yorùbá ní Nigeria a ti m’ólú
Ẹ̀yin ìgbà yẹn ni wọ́n fún wa ní òmìnira
Ní 1960 kó tó wá di pé a dá dúró
Ká tó gba Republic on the 1st of October 1963
Kí gbogbo ẹ̀ tó wá dàrú dàpọ̀ mọ́ wa lọ́wọ́
A ò f’ógun f’ọ́tẹ̀ ní ilẹ̀ yìí mọ́
Ohun tó bá wà níbẹ̀ ni á bá ara wa sọ
Bí ọmọ Yorùbá parapọ̀
Ṣẹe ara wa lọ́kàn o
Yorùbá parapọ̀ ká ṣe ara wa lọ́kàn o
Lágbájá ló ṣẹ̀ mí o
(ká má jà mọ́)
Àní Lágbájá ló ṣẹ̀ mí o
(Ká má jà mọ́)
Tàmẹ̀dù ló ṣẹ̀ mí o
(Ká má jà mọ́)
Tàmẹ̀dù ló ṣẹ̀ mí o
(Ká má jà mọ́)
Ẹ jẹ́ ká bá ara wa sọ̀rọ̀
(Ká má ṣe jà o)
Ẹ jẹ́ ká bá ara wa sọ̀rọ̀
(Ká má ṣe jà o)
Máyégún mà ti sọ̀rọ̀
(Ká má ṣe jà o)
Máyégún mà ti sọ̀rọ̀
(Ká má ṣe jà o)
Written by: Teni, Wasiu Ayinde Adewale Olasunkanmi Omogbolahan Anifowoshe
instagramSharePathic_arrow_out

Loading...