album cover
Moriamo
15,147
World
Moriamo was released on November 26, 2020 by YBBM as a part of the album Alagbe
album cover
AlbumAlagbe
Release DateNovember 26, 2020
LabelYBBM
Melodicness
Acousticness
Valence
Danceability
Energy
BPM95

Music Video

Music Video

Credits

Lyrics

[Intro]
Ọmọ Adefi
Ọmọ Adefa loke Iresi
(Mọriamọ Alegẹ, Mọriamọ)
[Verse 1]
Iya baba mi sun re
Ni ile aye 1980' something
(DaBeat Handle)
Damilare emi l'akọbi baami
Ki Qudus to di Qdot
Iya ati baba mi ti ja o ti pẹ
Ki n to waye l'ọn ti ni wọn le fẹra wọn
Okun ẹbi to ba ja welder kan o le jo, Alagbe
[Verse 2]
K'Ọlọhun fọrun kẹ Mọriamọ iya baba mi
Mọriamọ ọmọ Alegẹ
Iya ma n gbọmọ gẹgẹ ni
Mama o gbe mi silẹ k'eeyan kankan tọju mi
Mọriamọ ọrun re
Mi o gbagbe oko Alado o, lọna Erugbabu
Oko obi yi Grandma ti fọ loju kan
Boya n tori obi to ma ta ni Muri kan
Iya yi tun pada s'oko ada toun tọkọ ni
Ori mi a wu to ba pe l'ọkọ mi
Ọjọ ri jẹ pẹlu ọjọ riri mu
Mama ma n r'oka pẹlu ẹfọ bọkọlu
Omi odo la ma n mu (Omi odo la ma n mu)
[Verse 3]
L'abule Ado, l'abule Ado oh (Abule Ado, abule Ado)
Abule wa o jina si Shagamu
A n pada s'oko ni motor jamu (O ma ṣe)
Mama ba n pariwo Damilare, ọmọlọmọ ni e ba n gbe (O ma ṣe, o ma ṣe)
Ọjọ yẹn ni mo mọ pe iya yii kọ lo bi mi
[Chorus]
Mọriamọ Alegẹ (Mọriamọ)
Mọriamọ Alegẹ (Mọria oh)
Mọriamọ Alegẹ
Iya baba mi, ọrun re ẹ
[Chorus]
Mọriamọ Alegẹ
Mọriamọ Alegẹ (Mọria oh)
Mọriamọ Alegẹ
Iya baba mi, ọrun re ẹ (Mọriamọ)
Ọrun re ẹ (Mọria oh)
[Verse 4]
Hmm, ọjọ re bi ana nigba t'iku wọle de
Iya yii ti r'iku lo ṣe ni n boode lọ
K'oju mi ma ba r'ibi
Rafiu aburo mi n gba bọọlu nita
Mo wọle pada mọmọ ti d'oju bolẹ
[Verse 5]
Kayeefi lo jẹ, mo sare pe baba mi
Adio o wa dakun wa wo mama rẹ
A ṣọlọjọ lo de oh
Ngba t'ariwo ta, l'ọn bi wa ki lo de?
Ki n to mọ ẹsẹ ti pe
Shifau pẹlu Mutairu bẹrẹ si n'ke (Omije oh)
[Verse 6]
Wọn ni wọn o le sin mama
Mo ni ki lo de? Wọn ni ẹmi o jade tan (Ahh)
Ko fẹ fi mi silẹ lọ ni
Ọjọ ikeni lo, ikeji lọ
Ọjọ ikẹta, Mọria dagbere f'aye
[Chorus]
Mọriamọ Alegẹ (Mọriamọ)
Mọriamọ Alegẹ (Mọria oh)
Mọriamọ Alegẹ
Iya baba mi, ọrun re ẹ
[Chorus]
Mọriamọ Alegẹ (Mọriamọ)
Mọriamọ Alegẹ (Mọriamọ)
Mọriamọ Alegẹ
Iya baba mi, ọrun re ẹ (Mọriamọ)
Ọrun re ẹ (Mọriamọ oh)
[Verse 7]
Mọria dagbere f'aye
O digba, o digbere (Mọriamọ)
Mama Shifau, Mama Mutairu
Mọriamọ ọmọ Alegẹ, ọrun re ẹ
Ma royin ẹ f'ọmọ mi (Mọriamọ oh)
Mọriamọ, Mọriamọ oh
Mọriamọ (Mọriamọ)
Mọriamọ Alegẹ
[Outro]
Yeah, who's here?
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...