album cover
Mo Se Ba
album cover
Mo Se Ba was released on April 13, 2023 by Gospel Vibez Ltd. as a part of the album Igbowo Eda
April 13, 2023
LabelGospel Vibez Ltd.
BPM
Melodicness
Acousticness
Valence
Danceability
Energy

Music Video

Music Video

Lyrics

[Chorus]
Mo ṣeba f'Ọlọrun agbaye
Mo ṣeba f'Ọlọrun to ni ikawọ ohun gbogbo
Emi juba f'Ọlọrun to da ọrun ataye papọ
To lagbara lori ẹda gbogbo
[Chorus]
Mo ṣeba f'Ọlọrun agbaye (Alagbada ina)
Mo ṣeba f'Ọlọrun ikawọ gbogbo (Alawọtẹlẹ ooorun)
Mo juba f'Ọlọrun to da ọrun ataye papọ (Iwọ to da ọrun ate papọ)
To lagbara lori ẹda gbogbo
[Verse 1]
Eniyan meji n bimọ kan ṣoṣo
Ọkan ṣoṣo naa maa la wọn loogun gidi
Obi le bimọ meji kẹnu wọn ma ka wọn rara
You are mighty Ọlọrun ti ipa rẹ ka gbogbo aye, iwọ lo to bẹẹ
[Chorus]
Mo ṣeba f'Ọlọrun agbaye (Iwọ nikan naa ni)
Mo ṣeba f'Ọlọrun ikawọ gbogbo (Ẹnu rẹ ka gbogbo aye)
Mo juba f'Ọlọrun to da ọrun ataye papọ (To fi mọ isalu ọrun Baba o)
To lagbara lori ẹda gbogbo (Mo gbe fun iwọ nikan Ọlọrun gbogbo wa)
[Verse 2]
Wọn feniyan jẹ baalẹ tẹnu rẹ o ka aba
Ọba n jẹ lori ilu ti ilu o dẹ tori ẹ toro
Jinijini ti mu aarẹ wo ti ko roju ara rẹ
Aye o mi ọ ọrun n wa riri lorukọ rẹ (Aye o mi ọ)
[Chorus]
Mo ṣeba f'Ọlọrun agbaye (Ọrun n wa riri lorukọ rẹ)
Mo ṣeba f'Ọlọrun ikawọ gbogbo (Idọbalẹ lawọn agbaagba wa o)
Mo juba f'Ọlọrun to da ọrun ataye papọ (Ite to ga ju lọrun ataye)
To lagbara lori ẹda gbogbo (Mo grebe fun ọ Baba mi daadaa)
[Verse 3]
Iwọ l'Ọlọrun
Iwọ l'Oluwa
Iwọ l'Ọlọrun to pe ohun gbogbo wa
Ọrọ to laṣẹ lori ohun gbogbo to da o pata
Ẹni to o le mu ko si ninu iṣẹ ọwọ rẹ
O lagbara lori ẹda patapata
[Chorus]
Mo ṣeba f'Ọlọrun agbaye (Ko si ninu iṣẹ ọwọ rẹ)
Mo ṣeba f'Ọlọrun ikawọ gbogbo ( iwọ gan-an gan-an lọlọpaa ọrun)
Mo juba f'Ọlọrun to da ọrun ataye papọ (Amunimamabọ lorukọ rẹ)
To lagbara lori ẹda gbogbo (Iwọ nian lalagbara)
[Chorus]
Mo ṣeba f'Ọlọrun agbaye
Mo ṣeba f'Ọlọrun to ni ikawọ ohun gbogbo
Mo juba f'Ọlọrun to da ọrun ataye papọ
To lagbara lori ẹda gbogbo
[Verse 4]
Mo ṣeba oluda, nibo lo o le yi aye si?
Talo to ọ?
Talo ju ọ?
To ba paṣẹ fọjọ ko yi pada
Kabiesi ta ni o bi ọ?
Ọlọrun ẹran ara
Agbara rẹ lo ṣedidi ohun gbogbo
Iwọ to sọku di iye
Ẹlẹri ipin
Sababi ọrun to gbe aye duro wawa, o duro wamu
[Verse 5]
Olodumare
O ye kẹdaa gbogbo bẹru rẹ
Ọlọrun ogo
O ye kẹdaa gbogbo bẹru rẹ
[Verse 6]
Iwọ to ni eemi ati ẹmi inu
Ipilẹṣẹ aye ati ọrun wa ni ikawọ rẹ
Baba o
O ye kẹdaa gbogbo bẹru rẹ
Olodumare
Oye kẹda ma wa riri fun
Alagbara giga
O ye kẹda ma wa riri fun
[Verse 7]
Iwọ to o le pa to o le ji, o to tan, o to tan
Ṣikun aye ṣikun ọrun ta lo le gba a lọwọ rẹ
Ah, o ye kẹda ma wa riri fun
Olodumare o
O yẹ kẹdaa gbogbo bẹru rẹ
Awimayẹhun alagbara julọ
O yẹ kẹdaa gbogbo bẹru rẹ
[Verse 8]
Iwọ to ni eemi ati ẹmi inu
Ipilẹṣẹ aye ati ọrun wa ni ikawọ rẹ
Alagbara o
O yẹ kẹdaa gbogbo bẹru rẹ
Olodumare
O yẹ kẹda ma wa riri fun
Oniṣẹ iyanu
O yẹ kẹda ma wa riri fun
[Verse 9]
Iwọ to o le pa to o le ji, o to tan, o to tan
Ṣikun ọgbun ṣikun apadi n bẹ lọwọ rẹ
Baba o
O yẹ kẹda ma wa riri fun
[Outro]
Iba rẹ o Olodumare
Ogo ma ni fun ọ
Written by: Patricia Temitope Alabi
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...