album cover
Mo Taka Osi Danu
1,124
Gospel
Mo Taka Osi Danu was released on April 26, 2023 by Gospel Vibez Ltd. as a part of the album Mori Iyanu
album cover
Release DateApril 26, 2023
LabelGospel Vibez Ltd.
Melodicness
Acousticness
Valence
Danceability
Energy
BPM103

Music Video

Music Video

Credits

PERFORMING ARTISTS
Tope Alabi
Tope Alabi
Performer
COMPOSITION & LYRICS
Tope Alabi
Tope Alabi
Composer

Lyrics

[Chorus]
Mo taka oṣi danu (Mo taka)
Emi taka oṣi danu (Mo taka)
Oṣi ko maa yale mi
Ki n ma rinna kan oṣi
Oṣi ki n ṣe oun rere, Mo taka
Mo taka iya danu (Mo taka)
Emi taka iya danu (Mo taka)
Iya ko ma jẹ mi o
Ki n ma rinna jẹ iya
Iya ki n ṣe omi ọbẹ o, mo taka
[Chorus]
Ẹni to fẹ ire, ko nawọ
Ire wu emi ni temi
Aye ti mo wa, ki n ma jiya, ki n ma rinna kan oṣi
Ọlọrun to da mi, ko da mi fun iya
Ki n ma fi iya jẹ 'ra mi
Ijade, iwọle, atilọ, atibo, ire ko ma wo tẹ mi o
[Chorus]
Mo taka ofo danu (Mo taka)
Emi taka ofo danu (Mo taka)
Ofo ko ma ṣe mi o (Ko ma ṣe mi)
Ki n ma ṣofo laye mi o (Ki n ma s'ofo, t tọmo-tọmo)
Ofo ki n ṣẹ ohun rere, Mo taka
[Verse 1]
Ofo adanu ati ofo ori mi kọ ọ, mo taka ẹ sọnu
Ki n n ma sunkun, ki n ma fika bọnu, k'ọn ma bọ bata ofo sile mi
Ki n ma kawọ leri, fẹsẹ janlẹ, laye ti mo wa
K'ọn ma ma pejọ ba mi daro, kọfọ ma ṣe mi (Ọfọ ki n ṣe temi)
[Chorus]
Mo taka aisan danu (Mo taka), (Lorukọ Jesu o)
Emi taka were danu (Mo taka)
Aisan ko ma ṣe mi pa, ki n ma ma lọ ṣiwere (Ko ma fi kan mi)
Aisan ki n ṣe ohun rere, (Lorukọ Jesu) Mo taka
[Verse 2]
Gbogbo ọjọ lo buru, adura lo n ra igba pada
Ki ma ṣaisan, kaṣọ bora, otutu nigba oorun
Kori mi ma ṣe daru, ki n ma yawere ọsan gangan
K'ọn ma so mi mọlẹ kaisan ma pa daadaa pada saida laye mi (Laye ti mo wa)
[Verse 3]
Ẹ ma gbadura (Ẹ ma gbadura o)
Ẹ ma gbadura o (Ẹ ma gbadura o)
Ka ma toṣi, ka ma jiya (Ẹ ma gbadura o)
Aye buru ma, fi inu to ni (Ẹ ma gbadura o)
Ẹni to sunmọ ni gangan le ṣeni (Ẹ ma gbadura o)
Igba o hu loko eniyan lọ ṣeyan (Ẹ ma gbadura o)
Ibi ile-aye lo, ko ma ye mi o (Ẹ ma gbadura o)
Awa funra wa, ẹ jẹ ka ṣe daadaa (Ẹ ma gbadura o)
Ẹni ti o fẹ oṣi ko ma fọwọ fa oṣi (Ẹ ma gbadura o)
Kẹ ma tori ohun aye ka wa di were (Ẹ ma gbadura o)
Ka ma fọwọ ara wa baye ara wa jẹ (Ẹ ma gbadura o)
Ka ma gbero ọfọ seniyan, kọfọ ma ba ṣẹ wa (Ẹ ma gbadura o)
Tori a o le wa ninu ẹṣẹ ṣẹ gbọ (Ẹ ma gbadura o)
Ani koore ọfẹ ko ma pọsi (Ẹ ma gbadura o)
Ọlọrun o ṣebi, eniyan ni ka bẹ (Ẹ ma gbadura o)
Ẹ ma gbadura o (Ẹ ma gbadura o)
Ẹ dẹ ma fiye sinu (Ẹ ma gbadura o)
Ẹ ma gbadura o (Ẹ ma gbadura o)
Ẹ ma gbadura o (Ẹ ma gbadura o)
Written by: Patricia Temitope Alabi
instagramSharePathic_arrow_out􀆄 copy􀐅􀋲

Loading...